Orin Dafidi 73 BIBELI MIMỌ (BM)

Ìdájọ́ Òdodo Ọlọrun

1. Nítòótọ́ Ọlọrun ṣeun fún Israẹli,ó ṣeun fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́.

2. Ṣugbọn, ní tèmi, mo fẹ́rẹ̀ yọ̀ ṣubú,ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tàsé.

3. Nítorí mò ń ṣe ìlara àwọn onigbeeraganígbà tí mo rí ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú.

4. Wọn kì í jẹ ìrora kankan,ara wọn dá pé, ó sì jọ̀lọ̀.

5. Wọn kì í ní wahala bí àwọn ẹlòmíràn;ìyọnu tíí dé bá àwọn ẹlòmíràn kì í dé ọ̀dọ̀ wọn.

6. Nítorí náà, wọn á kó ìgbéraga bọ ọrùn bí ẹ̀gbà,wọn á fi ìwà ipá bora bí aṣọ.

7. Wọ́n sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú wọn yíbò;èrò òmùgọ̀ sì kún ọkàn wọn ní àkúnwọ́sílẹ̀.

8. Wọ́n ń pẹ̀gàn eniyan, wọ́n ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìlara;wọ́n sì ń fi ìgbéraga halẹ̀.

9. Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun;wọn a sì máa sọ̀rọ̀ ìgbéraga káàkiri ayé.

10. Nítorí náà, àwọn eniyan á yipada, wọn á fara mọ́ wọn,wọn á máa yìn wọ́n, láìbìkítà fún ibi tí wọn ń ṣe.

11. Wọn á máa wí pé, “Báwo ni Ọlọrun ṣe lè mọ̀?Ǹjẹ́ Ọ̀gá Ògo tilẹ̀ ní ìmọ̀?”

12. Ẹ wò ó! Ayé àwọn eniyan burúkú nìwọ̀nyí;ara dẹ̀ wọ́n nígbà gbogbo, ọrọ̀ wọn sì ń pọ̀ sí i.

13. Lásán ni gbogbo aáyan mi láti rí i pé ọkàn mi mọ́,tí mo sì yọwọ́-yọsẹ̀ ninu ibi.

14. Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni mò ń rí ìyọnu;láràárọ̀ ni à ń jẹ mí níyà.

15. Bí mo bá ní, “N óo sọ̀rọ̀ báyìí,”n óo kó àwọn ọmọ rẹ ṣìnà.

16. Ṣugbọn nígbà tí mo rò bí nǹkan wọnyi ṣe lè yé mi,mo rí i pé iṣẹ́ tíí dáni lágara ni.

17. Àfi ìgbà tí mo wọ ibi mímọ́ Ọlọrun lọ,ni mo tó wá rí òye ìgbẹ̀yìn wọn.

18. Nítòótọ́ ibi tí ń yọ̀ ni ó gbé wọn lé,ó sì mú kí wọn ṣubú sinu ìparun.

19. Wò ó bí wọn ṣe parun lọ́gán,tí ìpayà sì gbá wọn lọ patapata.

20. Wọ́n dàbí àlá tíí pòórá nígbà tí eniyan bá ta jí.OLUWA, nígbà tí o bá jí gìrì, wọn óo pòórá.

21. Nígbà tí ọkàn mí bàjẹ́,tí ọ̀rọ̀ náà gbóná lára mi,

22. mo hùwà òmùgọ̀, n kò sì lóye,mo sì dàbí ẹranko lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ.

23. Sibẹsibẹ nígbà gbogbo ni mo wà lọ́dọ̀ rẹ;o sì di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.

24. Ò ń fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi sọ́nà;lẹ́yìn náà, o óo sì gbà mí sinu ògo.

25. Ta ni mo ní lọ́run lẹ́yìn rẹ?Kò sì sí ohun kan tí ó wù mí láyé yìí bíkòṣe ìwọ.

26. Àárẹ̀ lè mú ara ati ẹ̀mí mi,ṣugbọn Ọlọrun ni agbára ẹ̀mí mi,ati ìpín mi títí lae.

27. Ó dájú pé àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóo ṣègbé,o óo sì pa àwọn tí ó bá ṣe alaiṣootọ sí ọ run.

28. Ní tèmi o, ó dára láti súnmọ́ Ọlọrun;mo ti fi ìwọ OLUWA Ọlọrun ṣe ààbò mi,kí n lè máa ròyìn gbogbo iṣẹ́ rẹ.