Orin Dafidi 99 BIBELI MIMỌ (BM)

Ọlọrun Ọba Atóbijù

1. OLUWA jọba, kí àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì;ó gúnwà lórí àwọn kerubu; kí ilẹ̀ mì tìtì.

2. OLUWA tóbi ní Sioni,ó sì jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè.

3. Jẹ́ kí wọ́n yin orúkọ rẹ tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù,mímọ́ ni OLUWA!

4. Ọba alágbára, ìwọ tí o fẹ́ràn òdodo,o ti fi ìdí ẹ̀tọ́ múlẹ̀;o ti dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ Jakọbu.

5. Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa,ẹ jọ́sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀;mímọ́ ni OLUWA!

6. Mose ati Aaroni wà lára àwọn alufaa rẹ̀;Samuẹli pàápàá wà lára àwọn tí ń pe orúkọ rẹ̀;wọ́n ké pe OLUWA ó sì dá wọn lóhùn.

7. Ó bá wọn sọ̀rọ̀ ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu;wọ́n pa òfin rẹ̀ mọ́;wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí ó fún wọn.

8. OLUWA Ọlọrun wa, o dá wọn lóhùn;Ọlọrun tíí dáríjì ni ni o jẹ́ fún wọn;ṣugbọn ó gbẹ̀san ìwàkiwà wọn.

9. Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa,kí ẹ sì jọ́sìn níbi òkè mímọ́ rẹ̀;nítorí pé mímọ́ ni OLUWA Ọlọrun wa.