Orin Dafidi 20 BIBELI MIMỌ (BM)

Adura Ìṣẹ́gun

1. OLUWA óo dá ọ lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú,orúkọ Ọlọrun Jakọbu óo dáàbò bò ọ́.

2. Yóo rán olùrànlọ́wọ́ sí ọ láti ilé mímọ́ rẹ̀ wá,yóo sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.

3. Yóo ranti gbogbo ẹbọ ọrẹ rẹ,yóo sì gba ẹbọ sísun rẹ.

4. Yóo fún ọ ní ohun tí o fẹ́ ninu ọkàn rẹ,yóo sì mú gbogbo èrò rẹ ṣẹ.

5. Ìhó ayọ̀ ni a óo hó nígbà tí o bá ṣẹgun,ní orúkọ Ọlọrun wa ni a óo sì fi ọ̀págun wa sọlẹ̀;OLUWA yóo dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ.

6. Mo wá mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA yóo ran ẹni àmì òróró rẹ̀ lọ́wọ́;OLUWA yóo dá a lóhùn láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wáyóo sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fún un ní ìṣẹ́gun ńlá.

7. Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun,àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin,ṣugbọn ní tiwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ OLUWA Ọlọrun wa.

8. Àwọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú,ṣugbọn àwa óo dìde, a óo sì dúró ṣinṣin.

9. Fún ọba ní ìṣẹ́gun, OLUWA;kí o sì dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń ké pè ọ́.