Orin Dafidi 133 BIBELI MIMỌ (BM)

Ìrẹ́pọ̀ Àwọn ará

1. Ó dára, ó sì dùn pupọ,bí àwọn ará bá ń gbé pọ̀ ní ìrẹ́pọ̀.

2. Ó dàbí òróró iyebíye tí a dà síni lórí,tí ó ṣàn dé irùngbọ̀n;bí ó ti ṣàn dé irùngbọ̀n Aaroni,àní, títí dé ọrùn ẹ̀wù rẹ̀.

3. Ó dàbí ìrì òkè Herimoni,tí ó sẹ̀ sórí òkè Sioni.Níbẹ̀ ni OLUWA ti ṣe ìlérí ibukun,àní, ìyè ainipẹkun.