Orin Dafidi 24 BIBELI MIMỌ (BM)

Ọba Atóbijù

1. OLUWA ló ni ilẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó wàninu rẹ̀,òun ló ni ayé, ati gbogbo àwọn tíń gbé inú rẹ̀;

2. nítorí pé òun ló fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí òkun,ó sì gbé e kalẹ̀ lórí ìṣàn omi.

3. Ta ló lè gun orí òkè OLUWA lọ?Ta ló sì lè dúró ninu ibi mímọ́ rẹ̀?

4. Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́, tí inú rẹ̀ sì funfun,tí kò gbẹ́kẹ̀lé oriṣa lásánlàsàn,tí kò sì búra èké.

5. Òun ni yóo rí ibukun gbà lọ́dọ̀ OLUWA,tí yóo sì rí ìdáláre gbà lọ́wọ́ Ọlọrun, Olùgbàlà rẹ̀.

6. Irú wọn ni àwọn tí ń wá OLUWA,àní àwọn tí ń wá ojurere Ọlọrun Jakọbu.

7. Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn,ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,kí Ọba ògo lè wọlé.

8. Ta ni Ọba ògo yìí?OLUWA tí ó ní ipá tí ó sì lágbára,OLUWA tí ó lágbára lógun.

9. Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn,ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,kí Ọba ògo lè wọlé.

10. Ta ni Ọba ògo yìí?OLUWA àwọn ọmọ ogun,òun ni Ọba ògo náà.