Orin Dafidi 100 BIBELI MIMỌ (BM)

Orin Ìyìn

1. Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA, gbogbo ilẹ̀ ayé.

2. Ẹ fi ayọ̀ sin OLUWA.Ẹ wá siwaju rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀.

3. Ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ni Ọlọrun,òun ló dá wa, òun ló ni wá;àwa ni eniyan rẹ̀,àwa sì ni agbo aguntan rẹ̀.

4. Ẹ wọ ẹnubodè rẹ̀ tẹ̀yin tọpẹ́,kí ẹ sì wọ inú àgbàlá rẹ̀ tẹ̀yin tìyìn.Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀,kí ẹ sì máa yin orúkọ rẹ̀.

5. Nítorí OLUWA ṣeun;ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae,òtítọ́ rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.