Orin Dafidi 16 BIBELI MIMỌ (BM)

Mo Sá di OLUWA

1. Pa mí mọ́ Ọlọrun, nítorí ìwọ ni mo sá di.

2. Mo wí fún ọ, OLUWA, pé, “Ìwọ ni Oluwa mi;ìwọ nìkan ni orísun ire mi.”

3. Nípa àwọn eniyan mímọ́ tí ó wà nílẹ̀ yìí,wọ́n jẹ́ ọlọ́lá tí àwọn eniyan fẹ́ràn.

4. “Ìbànújẹ́ àwọn tí ń sá tọ ọlọrun mìíràn lẹ́yìn yóo pọ̀:Èmi kò ní bá wọn ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ fún ìrúbọ,bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò ní gbọ́ orúkọ wọn lẹ́nu mi.”

5. OLUWA, ìwọ ni ìpín mi, ìwọ ni mo yàn;ìwọ ni ò ń jẹ́ kí ọ̀ràn mi fìdí múlẹ̀.

6. Ìpín tí ó bọ́ sí mi lọ́wọ́ dára pupọ;ogún rere ni ogún ti mo jẹ.

7. Èmi óo máa yin OLUWA, ẹni tí ó ń fún mi ní òye;ọkàn mi ó sì máa tọ́ mi sọ́nà ní òròòru.

8. Mò ń wo OLUWA ní iwájú mi nígbà gbogbo,nítorí pé Ọlọrun dúró tì mí, ẹsẹ̀ mi kò ní yẹ̀.

9. Nítorí náà ni ọkàn mi ṣe ń yọ̀, tí inú mi dùn;ara sì rọ̀ mí.

10. Nítorí o kò ní gbàgbé mi sí ipò òkú,bẹ́ẹ̀ ni o kò ní jẹ́ kí ẹni tí ó fi tọkàntọkàn sìn ọ́ rí ìdíbàjẹ́.

11. O ti fi ọ̀nà ìyè hàn mí;ayọ̀ kíkún ń bẹ ní iwájú rẹ,ìgbádùn àìlópin sì ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.