Orin Dafidi 117 BIBELI MIMỌ (BM)

Yíyin OLUWA

1. Ẹ máa yin OLUWA, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè!Ẹ yìn ín gbogbo ẹ̀yin eniyan,

2. Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ tóbi sí wa,òtítọ́ rẹ̀ sì wà títí laelae.Ẹ máa yin OLUWA.