Orin Dafidi 132 BIBELI MIMỌ (BM)

Majẹmu Ọlọrun pẹlu Ìdílé Dafidi

1. OLUWA, ranti gbogbo ìyà tí Dafidi fara dà.

2. Ranti bí ó ṣe búra fún OLUWA,tí ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu,

3. tí ó ní, “N kò ní wọ inú ilé mi,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní bọ́ sí orí ibùsùn mi;

4. n kò ní sùn,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní tòògbé,

5. títí tí n óo fi wá ààyè fún OLUWA,àní, tí n óo fi pèsè ibùgbé fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu.”

6. A gbúròó rẹ̀ ní Efurata,a rí i ní oko Jearimu.

7. “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ibùgbé rẹ̀;ẹ jẹ́ kí á lọ wólẹ̀ níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.”

8. Dìde, OLUWA, lọ sí ibi ìsinmi rẹ,tìwọ ti àpótí agbára rẹ.

9. Jẹ́ kí àwọn alufaa rẹ wọ ẹ̀wù òdodo,kí àwọn eniyan mímọ́ rẹ sì máa kọrin ayọ̀.

10. Nítorí ti Dafidi, iranṣẹ rẹ,má jẹ́ kí ẹni tí a fi òróró rẹ yàn yíjú kúrò lára rẹ.

11. OLUWA ti ṣe ìbúra tí ó dájú fún Dafidi,èyí tí kò ní yipada; ó ní,“Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹni n óo gbé ka orí ìtẹ́ rẹ.

12. Bí àwọn ọmọ rẹ bá pa majẹmu mi mọ́,tí wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí n óo fi lélẹ̀ fún wọn,àwọn ọmọ tiwọn náà óo jókòó lórí ìtẹ́ rẹ títí lae.”

13. Nítorí OLUWA ti yan Sioni;ó fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀:

14. Ó ní, “Ìhín ni ibi ìsinmi mi títí lae,níhìn-ín ni n óo máa gbé, nítorí pé ó wù mí.

15. N óo bù sí oúnjẹ rẹ̀ lọpọlọpọ;n óo fi oúnjẹ tẹ́ àwọn aláìní ibẹ̀ lọ́rùn.

16. N óo gbé ẹ̀wù ìgbàlà wọ àwọn alufaa rẹ̀,àwọn eniyan mímọ́ rẹ̀ yóo sì kọrin ayọ̀.

17. Níbẹ̀ ni n óo ti fún Dafidi ní agbára;mo ti gbé àtùpà kalẹ̀ fún ẹni tí mo fi òróró yàn.

18. N óo da ìtìjú bo àwọn ọ̀tá rẹ̀ bí aṣọ,ṣugbọn adé orí rẹ̀ yóo máa tàn yinrinyinrin.”