Orin Dafidi 127 BIBELI MIMỌ (BM)

Abániṣé ni OLUWA

1. Bí OLUWA kò bá kọ́ ilé,asán ni wahala àwọn tí ń kọ́ ọ.Bí OLUWA kò bá ṣọ́ ìlú,asán ni àìsùn àwọn aṣọ́de.

2. Asán ni kí á jí ní òwúrọ̀ kutukutu,kí á tún pẹ́ títí kí á tó sùn.Asán ni kí á máa fi làálàá wá oúnjẹ;nítorí pé OLUWA a máa fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ ní oorun sùn.

3. Wò ó! Ẹ̀bùn OLUWA ni ọmọ;òun ní fi oyún inú ṣìkẹ́ eniyan.

4. Bí ọfà ti rí lọ́wọ́ jagunjagun,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ìgbà òwúrọ̀ ẹni.

5. Ayọ̀ ń bẹ fun ẹni tí apó rẹ̀ kún fún wọn.Ojú kò ní tì í nígbà tí ó bá ń bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ rojọ́ lẹ́nu bodè.