Orin Dafidi 63 BIBELI MIMỌ (BM)

Wíwá Ọlọrun

1. Ọlọrun, ìwọ ni Ọlọrun mi, mò ń wá ọ,ọkàn rẹ ń fà mí;bí ilẹ̀ tí ó ti ṣá, tí ó sì gbẹṣe máa ń kóǹgbẹ omi.

2. Mo ti ń wò ọ́ ninu ilé mímọ́ rẹ,mo ti rí agbára ati ògo rẹ.

3. Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára ju ìyè lọ,n óo máa yìn ọ́.

4. N óo máa yìn ọ́ títí ayé mi;n óo máa tẹ́wọ́ adura sí ọ.

5. Ẹ̀mí mi yóo ní ànító ati àníṣẹ́kù;n óo sì fi ayọ̀ kọ orin ìyìn sí ọ.

6. Nígbà tí mo bá ranti rẹ lórí ibùsùn mi,tí mo bá ń ṣe àṣàrò nípa rẹ ní gbogbo òru;

7. nítorí ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi,lábẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ ni mò ń fi ayọ̀ kọrin.

8. Ẹ̀mí mi rọ̀ mọ́ ọ;ọwọ́ ọ̀tun rẹ ni ó gbé mi ró.

9. Ṣugbọn àwọn tí ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí miyóo sọ̀kalẹ̀ lọ sinu isà òkú.

10. A ó fi idà pa wọ́n lójú ogun,ẹranko ni yóo sì jẹ òkú wọn.

11. Ṣugbọn ọba yóo máa yọ̀ ninu Ọlọrun;gbogbo àwọn tí ń fi orúkọ OLUWA búrayóo máa fògo fún un;ṣugbọn a ó pa àwọn òpùrọ́ lẹ́nu mọ́.