Orin Dafidi 33 BIBELI MIMỌ (BM)

Orin Ìyìn

1. Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo!Yíyin OLUWA ni ó yẹ ẹ̀yin olóòótọ́.

2. Ẹ fi gòjé yin OLUWA,ẹ fi hapu olókùn mẹ́wàá kọ orin sí i.

3. Ẹ kọ orin titun sí i,ẹ fi ohun èlò ìkọrin olókùn dárà,kí ẹ sì hó ìhó ayọ̀.

4. Nítorí ọ̀rọ̀ OLUWA dúró ṣinṣin;òtítọ́ sì ni ó fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.

5. OLUWA fẹ́ràn òdodo ati ẹ̀tọ́;ayé kún fún ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.

6. Ọ̀rọ̀ ni OLUWA fi dá ojú ọ̀run,èémí ẹnu rẹ̀ ni ó sì fi dá oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀.

7. Ó wọ́ gbogbo omi òkun jọ bí òkìtì;ó pa gbogbo omi inú àwọn ibú pọ̀ bí ẹni pé ó rọ ọ́ sinu àgbá ńlá.

8. Kí gbogbo ayé bẹ̀rù OLUWA,kí gbogbo aráyé dúró níwájú rẹ̀ pẹlu ọ̀wọ̀ ati ìbẹ̀rù!

9. Nítorí pé OLUWA sọ̀rọ̀, ayé wà;ó pàṣẹ, ayé sì dúró.

10. OLUWA sọ ìmọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè di asán;ó sì mú kí ètò àwọn eniyan já sófo.

11. Ètò OLUWA wà títí lae,èrò ọkàn rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.

12. Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn,àní àwọn eniyan tí ó yàn gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀!

13. OLUWA bojúwo ilẹ̀ láti ọ̀run,ó rí gbogbo eniyan;

14. láti orí ìtẹ́ rẹ̀ tí ó gúnwà sí,ó wo gbogbo aráyé.

15. Òun ni ó dá ọkàn gbogbo wọn,tí ó sì ń mójútó gbogbo ìṣe wọn.

16. Kì í ṣe pípọ̀ tí àwọn ọmọ ogun pọ̀ ní ń gba ọba là;kì í sì í ṣe ọ̀pọ̀ agbára níí gba jagunjagun là.

17. Asán ni igbẹkẹle agbára ẹṣin ogun;kìí ṣe agbára tí ẹṣin ní, ló lè gbani là.

18. Wò ó! OLUWA ń ṣọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,àní àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,

19. kí ó lè gba ọkàn wọn lọ́wọ́ ikú,kí ó sì mú wọn wà láàyè lákòókò ìyàn.

20. Ọkàn wa ní ìrètí lọ́dọ̀ OLUWA;òun ni olùrànlọ́wọ́ ati ààbò wa.

21. A láyọ̀ ninu rẹ̀,nítorí pé a gbẹ́kẹ̀lé orúkọ mímọ́ rẹ̀.

22. OLUWA, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà lórí wabí a ti gbẹ́kẹ̀lé ọ.