Orin Dafidi 134 BIBELI MIMỌ (BM)

Ẹ yin OLUWA

1. Ẹ wá, ẹ yin OLUWA,gbogbo ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ń sìn ín ninu ilé rẹ̀ lóru.

2. Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè, kí ẹ gbadura ninu ilé mímọ́ rẹ̀,kí ẹ sì yin OLUWA.

3. Kí OLUWA tí ó dá ọ̀run ati ayébukun yín láti Sioni wá.