Orin Dafidi 14 BIBELI MIMỌ (BM)

Èrè Òmùgọ̀

1. Òmùgọ̀ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Ọlọrun kò sí.”Wọ́n bàjẹ́, ohun ìríra ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn,kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ń ṣe rere.

2. OLUWA bojú wo ilẹ̀, láti ọ̀run wá,ó wo àwọn ọmọ eniyan,láti mọ̀ bí àwọn kan bá wà tí wọ́n gbọ́n,tí wọn ń wá Ọlọrun.

3. Gbogbo wọn ti ṣìnà,gbogbo wọn pátá ni wọ́n sì ti bàjẹ́;kò sí ẹnìkan tí ń ṣe rere,kò sí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo.

4. Ṣé gbogbo àwọn aṣebi kò gbọ́n ni?Àwọn tí ń jẹ eniyan mi bí ẹni jẹun,àwọn tí kì í ké pe OLUWA.

5. Níbẹ̀ ni a óo ti dẹ́rù bà wọ́n gidigidi,nítorí Ọlọrun ń bẹ pẹlu àwọn olódodo.

6. Ẹ̀yin ń fẹ́ da ètò aláìní rú,ṣugbọn OLUWA ni ààbò rẹ̀.

7. Ìbá ti dára tó kí ìgbàlà Israẹli ti Sioni wá!Nígbà tí OLUWA bá dá ire àwọn eniyan rẹ̀ pada,Jakọbu yóo yọ̀, inú Israẹli yóo sì dùn.