Orin Dafidi 125 BIBELI MIMỌ (BM)

Ìfọ̀kànbalẹ̀ Àwọn Eniyan OLUWA

1. Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA dàbí òkè Sioni,tí ẹnikẹ́ni kò lè ṣí nídìí, ṣugbọn tí ó wà títí lae.

2. Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yí àwọn eniyan rẹ̀ ká,láti ìsinsìnyìí lọ ati títí lae.

3. Eniyan burúkú kò ní ní àṣẹlórí ilẹ̀ àwọn olódodo,kí àwọn olódodo má baà dáwọ́ lé ibi.

4. OLUWA, ṣe oore fún àwọn eniyan rere,ati fún àwọn olódodo.

5. Ṣugbọn OLUWA yóo fi irú ìyà àwọn aṣebi jẹàwọn tí ó yà sí ọ̀nà àìtọ́.Alaafia fún Israẹli!