Àwọn Ọba Kinni 11:15-26 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ṣáájú àkókò yìí, nígbà tí Dafidi gbógun ti àwọn ará Edomu, tí ó sì ṣẹgun wọn, Joabu balogun rẹ̀ lọ sin àwọn tí wọ́n kú sógun, ó sì pa gbogbo àwọn ọmọkunrin Edomu;

16. nítorí pé Joabu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wà ní ilẹ̀ Edomu fún oṣù mẹfa, títí tí ó fi pa gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Edomu run.

17. Ṣugbọn Adadi ati díẹ̀ lára àwọn iranṣẹ baba rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ ará Edomu sá lọ sí ilẹ̀ Ijipti, Adadi kéré pupọ nígbà náà.

18. Adadi ati àwọn iranṣẹ baba rẹ̀ wọnyi kúrò ní Midiani, wọ́n sì lọ sí Parani. Ní Parani yìí ni àwọn ọkunrin mìíràn ti para pọ̀ mọ́ wọn, tí gbogbo wọ́n sì jọ lọ sí Ijipti. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Farao, ọba Ijipti, ó fún Adadi ní ilé ati ilẹ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún un déédé.

19. Adadi bá ojurere Farao ọba pàdé, ọba bá fi arabinrin ayaba Tapenesi, iyawo rẹ̀, fún Adadi kí ó fi ṣe aya.

20. Arabinrin ayaba Tapenesi yìí bí ọmọkunrin kan fún Adadi, ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Genubati. Inú ilé Farao ọba ni ayaba Tapenesi ti tọ́ ọmọ náà dàgbà, láàrin àwọn ọmọ ọba.

21. Nígbà tí Adadi gbọ́ ní Ijipti pé Dafidi ọba ti kú, ati pé Joabu, balogun rẹ̀ náà ti kú, ó wí fún Farao pé, “Jẹ́ kí n pada lọ sí ìlú mi.”

22. Farao bá bi í léèrè pé, “Kí lo fẹ́ tí o kò rí lọ́dọ̀ mi, tí o fi fẹ́ máa lọ sí ìlú rẹ?”Ṣugbọn Adadi dá a lóhùn pé, “Ṣá jẹ́ kí n máa lọ.”

23. Ọlọrun tún mú kí Resoni ọmọ Eliada dojú ọ̀tá kọ Solomoni, sísá ni Resoni yìí sá kúrò lọ́dọ̀ Hadadeseri, ọba Soba, tí ó jẹ́ ọ̀gá rẹ̀.

24. Lẹ́yìn tí Dafidi ti ṣẹgun Hadadeseri ọba, tí ó sì ti pa àwọn ará Siria tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀, Resoni di olórí àwọn ìgárá ọlọ́ṣà kan tí wọ́n kó ara wọn jọ, tí wọn ń gbé Damasku. Àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá fi jọba ní Damasku.

25. Ọ̀tá gidi ni ó jẹ́ fún Israẹli ní ìgbà ayé Solomoni, ó sì ṣe jamba bí Hadadi ti ṣe. Ó kórìíra àwọn ọmọ Israẹli, òun sì ni ọba ilẹ̀ Siria.

26. Ẹnìkan tí ó tún kẹ̀yìn sí Solomoni ni ọ̀kan ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tí ń jẹ́ Jeroboamu, ọmọ Nebati, ará Sereda, ninu ẹ̀yà Efuraimu, obinrin opó kan tí ń jẹ́ Serua ni ìyá rẹ̀.

Àwọn Ọba Kinni 11