6. Àwọn eniyan ń retí pé ọwọ́ rẹ̀ yóo wú, tabi pé lójijì yóo ṣubú lulẹ̀, yóo sì kú. Nígbà tí wọ́n retí títí, tí wọn kò rí i kí nǹkankan ṣe é, wọ́n yí èrò wọn pada, wọ́n ní, “Irúnmọlẹ̀ ni!”
7. Ilẹ̀ tí ó wá yí wọn ká jẹ́ ti Pubiliusi, baálẹ̀ erékùṣù náà. Ó gbà wá sílé fún ọjọ́ mẹta, ó sì ṣe wá lálejò.
8. Ní àkókò yìí baba Pubiliusi ń ṣàìsàn: ibà ń ṣe é, ó sì ń ya ìgbẹ́-ọ̀rìn. Paulu bá wọ iyàrá tọ̀ ọ́ lọ. Lẹ́yìn tí ó gbadura, ó gbé ọwọ́ lé e, ó sì wò ó sàn.
9. Nígbà tí èyí ṣẹlẹ̀, àwọn yòókù tí ó ń ṣàìsàn ní erékùṣù náà bá ń wá sọ́dọ̀ Paulu, ó sì ń wò wọ́n sàn.
10. Wọ́n yẹ́ wa sí pupọ. Nígbà tí a óo sì fi ṣíkọ̀, wọ́n fún wa ní àwọn nǹkan tí a lè nílò lọ́nà.
11. Lẹ́yìn oṣù mẹta tí a ti wà níbẹ̀, a wọ ọkọ̀ ojú omi Alẹkisandria kan tí ó ti dúró ní erékùṣù yìí fún ìgbà òtútù. Ó ní ère ìbejì níwájú rẹ̀.
12. Nígbà tí a dé Sirakusi, a dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹta.
13. Láti ibẹ̀ a ṣíkọ̀, a dé Regiumu. Ní ọjọ́ keji, afẹ́fẹ́ kan láti gúsù fẹ́ wá, ni a bá tún ṣíkọ̀. Ní ọjọ́ kẹta a dé Puteoli.
14. A rí àwọn onigbagbọ níbẹ̀. Wọ́n rọ̀ wá kí á dúró lọ́dọ̀ wọn, a bá ṣe ọ̀sẹ̀ kan níbẹ̀. Báyìí ni a ṣe dé Romu.
15. Àwọn onigbagbọ ibẹ̀ ti gbọ́ ìròyìn wa. Wọ́n bá wá pàdé wa lọ́nà, wọ́n dé Ọjà Apiusi ati Ilé-èrò Mẹta. Nígbà tí Paulu rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, èyí sì dá a lọ́kàn le.
16. Nígbà tí a wọ Romu, wọ́n gba Paulu láàyè láti wá ilé gbé pẹlu ọmọ-ogun kan tí wọ́n fi ṣọ́ ọ.
17. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta Paulu pe àwọn aṣiwaju àwọn Juu jọ. Nígbà tí ẹsẹ̀ wọn pé, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin alàgbà, n kò ṣe ohunkohun tí ó lòdì sí àwọn eniyan wa tabi sí àṣà àwọn baba ńlá wa tí wọ́n fi fi mí lé àwọn ará Romu lọ́wọ́ tí wọ́n sì fi mí sinu ẹ̀wọ̀n láti Jerusalẹmu.
18. Nígbà tí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu mi, wọ́n fẹ́ dá mi sílẹ̀ nítorí wọn kò rí ohunkohun tí mo ṣe tí wọ́n fi lè dá mi lẹ́bi ikú.
19. Ṣugbọn nígbà tí àwọn Juu kò gbà pé kí wọ́n dá mi sílẹ̀, kò sí ohun tí mo tún lè ṣe jù pé kí n gbé ẹjọ́ mi wá siwaju Kesari lọ. Kì í ṣe pé mo ní ẹjọ́ kankan láti bá orílẹ̀-èdè wa rò.
20. Ìdí nìyí tí mo fi ranṣẹ pè yín láti ri yín kí n sì ba yín sọ̀rọ̀; nítorí ohun tí Israẹli ń retí ni wọ́n ṣe fi ẹ̀wọ̀n so mí báyìí.”
21. Wọ́n dá a lóhùn pé, “A kò rí ìwé gbà nípa rẹ láti Judia; bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni ninu àwọn ará wa kò débí láti ròyìn rẹ tabi láti sọ̀rọ̀ rẹ ní ibi.
22. A rò pé ó dára kí á gbọ́ ohun tí o ní lọ́kàn, nítorí pé ó ti dé etígbọ̀ọ́ wa pé níbi gbogbo ni àwọn eniyan lòdì sí ẹgbẹ́ tí ó yàtọ̀ yìí.”