12. Nitorina pipọ ninu wọn gbagbọ́; ati ninu awọn obinrin Hellene ọlọlá, ati ninu awọn ọkunrin, kì iṣe diẹ.
13. Ṣugbọn nigbati awọn Ju ti Tessalonika mọ̀ pe, Paulu nwasu ọ̀rọ Ọlọrun ni Berea, nwọn si wá sibẹ̀ pẹlu, nwọn rú awọn enia soke.
14. Nigbana li awọn arakunrin rán Paulu jade lọgan lati lọ titi de okun: Ṣugbọn Sila on Timotiu duro sibẹ̀.
15. Awọn ti o sin Paulu wá si mu u lọ titi de Ateni; nigbati nwọn si gbà aṣẹ lọdọ rẹ̀ tọ̀ Sila on Timotiu wá pe, ki nwọn ki o yára tọ̀ on wá, nwọn lọ.
16. Nigbati Paulu duro dè wọn ni Ateni, ọkàn rẹ̀ rú ninu rẹ̀, nigbati o ri pe ilu na kún fun oriṣa.
17. Nitorina o mba awọn Ju fi ọ̀rọ̀ we ọ̀rọ̀ ninu sinagogu, ati awọn olufọkansin, ati awọn ti o mba pade lọja lojojumọ.
18. Ninu awọn Epikurei pẹlu, ati awọn ọjọgbọ́n Stoiki kótì i. Awọn kan si nwipe, Kili alahesọ yi yio ri wi? awọn miran si wipe, O dabi oniwasu ajeji oriṣa: nitoriti o nwasu Jesu, on ajinde fun wọn.
19. Nwọn si mu u, nwọn si fà a lọ si Areopagu, nwọn wipe, A ha le mọ̀ kili ẹkọ́ titun ti iwọ nsọrọ rẹ̀ yi jẹ́.
20. Nitoriti iwọ mu ohun ajeji wá si etí wa: awa si nfẹ mọ̀ kini itumọ nkan wọnyi.
21. Nitori gbogbo awọn ará Ateni, ati awọn alejò ti nṣe atipo nibẹ kì iṣe ohun miran jù, ki a mã sọ tabi ki a ma gbọ́ ohun titun lọ.
22. Paulu si dide duro larin Areopagu, o ni, Ẹnyin ará Ateni, mo woye pe li ohun gbogbo ẹ kun fun oniruru isin ju.
23. Nitori bi mo ti nkọja lọ, ti mo wò ohun wọnni ti ẹnyin nsìn, mo si ri pẹpẹ kan ti a kọ akọle yi si, FUN ỌLỌRUN AIMỌ̀. Njẹ ẹniti ẹnyin nsìn li aimọ̀ on na li emi nsọ fun nyin.
24. Ọlọrun na ti o da aiye ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, on na ti iṣe Oluwa ọrun on aiye, kì igbé ile ti a fi ọwọ́ kọ́;
25. Bẹ̃ni a kì ifi ọwọ́ enia sìn i, bi ẹnipe o nfẹ nkan, on li o fi ìye ati ẽmi ati ohun gbogbo fun gbogbo enia,
26. O si ti fi ẹ̀jẹ kanna da gbogbo orilẹ-ede lati tẹ̀do si oju agbaiye, o si ti pinnu akokò ti a yàn tẹlẹ, ati àla ibugbe wọn;
27. Ki nwọn ki o le mã wá Oluwa, boya bi ọkàn wọn ba le fà si i, ti wọn si ri i, bi o tilẹ ṣe pe kò jina si olukuluku wa:
28. Nitori ninu rẹ̀ li awa gbé wà li ãye, ti awa nrìn kiri, ti a si li ẹmí wa; bi awọn kan ninu awọn olorin, ẹnyin tikaranyin ti wipe, Awa pẹlu si jẹ ọmọ rẹ̀.