Kọrinti Kinni 7:16-28 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Nítorí, ta ni ó mọ̀, bóyá ìwọ aya ni yóo gba ọkọ rẹ là? Tabi ta ni ó mọ̀, ìwọ ọkọ, bóyá ìwọ ni o óo gba aya rẹ là?

17. Kí olukuluku máa gbé ìgbé-ayé rẹ̀ bí Oluwa ti yàn án fún un, kí ó sì wà ní ipò tí ó wà nígbà tí Ọlọrun fi pè é láti di onigbagbọ. Bẹ́ẹ̀ ni mò ń fi kọ́ gbogbo àwọn ìjọ.

18. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ ẹni tí ó kọlà nígbà tí a pè é, kí ó má ṣe pa ilà rẹ̀ rẹ́. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ aláìkọlà nígbà tí a pè é, kí ó má ṣe kọlà.

19. Ati a kọlà ni, ati a kò kọlà ni, kò sí èyí tí ó ṣe pataki. Ohun tí ó ṣe pataki ni pípa àwọn òfin Ọlọrun mọ́.

20. Kí olukuluku wà ní ipò tí ó wà nígbà tí a pè é láti di onigbagbọ.

21. Ẹrú ni ọ́ nígbà tí a fi pè ọ́? Má ṣe gbé e lékàn. Ṣugbọn bí o bá ní anfaani láti di òmìnira, lo anfaani rẹ.

22. Nítorí ẹrú tí a pè láti di onigbagbọ di òmìnira lọ́dọ̀ Oluwa. Bákan náà ni, ẹni òmìnira tí a pè láti di onigbagbọ di ẹrú Kristi.

23. Iyebíye ni Ọlọrun rà yín. Ẹ má ṣe di ẹrú eniyan mọ́.

24. Ẹ̀yin ará, ipòkípò tí olukuluku bá wà tí a bá fi pè é, níbẹ̀ ni kí ó máa wà níwájú Ọlọrun.

25. N kò ní àṣẹ kan láti ọ̀dọ̀ Oluwa láti pa fún àwọn wundia. Ṣugbọn mò ń sọ ohun tí mo rò gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Oluwa ti ṣàánú fún, tí eniyan sì lè gbẹ́kẹ̀lé.

26. Mo rò pé ohun tí ó dára ni pé kí eniyan má ṣe kúrò ní ipò tí ó wà, nítorí àkókò ìpọ́njú ni àkókò yìí.

27. Bí o bá ti gbé iyawo, má ṣe wá ọ̀nà láti kọ aya rẹ. Bí o bá sì ti kọ aya rẹ, má ṣe wá ọ̀nà láti tún gbé iyawo.

28. Ṣugbọn bí o bá gbeyawo, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀. Bí wundia náà bá sì lọ́kọ, kò dẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn irú àwọn bẹ́ẹ̀ yóo ní ìpọ́njú ní ti ara. Bẹ́ẹ̀ ni n kò sì fẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ si yín.

Kọrinti Kinni 7