1. Agiripa wá yíjú sí Paulu, ó ní, “Ọ̀rọ̀ kàn ọ́. Sọ tìrẹ.” Paulu bá nawọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí ro ẹjọ́ tirẹ̀. Ó ní:
2. “Agiripa Ọba Aláyélúwà, mo ka ara mi sí olóríire pé níwájú yín ni n óo ti dáhùn sí gbogbo ẹjọ́ tí àwọn Juu pè mí lónìí,
3. pàápàá nítorí ẹ mọ gbogbo àṣà àwọn Juu dáradára, ẹ sì mọ àríyànjiyàn tí ó wà láàrin wọn. Nítorí náà mo bẹ̀ yín kí ẹ fi sùúrù gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.
4. “Gbogbo àwọn Juu ni wọ́n mọ̀ bí mo ti lo ìgbésí ayé mi láti ìbẹ̀rẹ̀ ní ìgbà èwe mi nígbà tí mò ń gbé Jerusalẹmu láàrin àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè wa.
5. Ó ti pẹ́ tí wọ́n ti mọ̀ mí. Bí wọn bá fẹ́, wọ́n lè jẹ́rìí sí i pé ọ̀nà àwọn Farisi ni mo tẹ̀lé ninu ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wa, ọ̀nà yìí ló sì le jù.
6. Wàyí ò! Ohun tí ó mú mi dúró nílé ẹjọ́ nisinsinyii ni pé mo ní ìrètí pé ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba wa yóo ṣẹ.
7. Ìrètí yìí ni àwọn ẹ̀yà mejila tí ó wà ní orílẹ̀-èdè wa ní, tí wọ́n ṣe ń fi ìtara sin Ọlọrun tọ̀sán-tòru. Nítorí ohun tí à ń retí yìí ni àwọn Juu fi ń rojọ́ mi, Kabiyesi!
8. Kí ló ṣe wá di ohun tí ẹnikẹ́ni ninu yín kò lè gbàgbọ́ pé Ọlọrun a máa jí òkú dìde?”
9. “Nígbà kan rí èmi náà rò pé ó jẹ mí lógún láti tako orúkọ Jesu ará Nasarẹti. Kí ni n ò ṣe tán?
10. Mo ṣe díẹ̀ ní Jerusalẹmu. Pupọ ninu àwọn onigbagbọ ni mo tì mọ́lé, lẹ́yìn tí mo ti gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn olórí alufaa. Wọn á máa pa wọ́n báyìí, èmi náà á sì ní bẹ́ẹ̀ gan-an ló yẹ wọ́n.
11. Mò ń lọ láti ilé ìpàdé kan dé ekeji, mo sì ń jẹ wọ́n níyà, bóyá wọn a jẹ́ fẹnu wọn gbẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀tanú náà pọ̀ sí wọn tó bẹ́ẹ̀ tí mo fi lé wọn dé ìlú òkèèrè pàápàá.
12. “Irú eré báyìí ni mò ń sá tí mò fi ń lọ sí Damasku ní ọjọ́ kan, pẹlu ìwé àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa.
13. Kabiyesi, bí mo ti ń lọ lọ́nà lọ́sàn-án gangan, mo rí ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀run tí ó mọ́lẹ̀ ju ti oòrùn lọ, tí ó tàn yí èmi ati àwọn tí ń bá mi lọ ká.
14. Bí gbogbo wa ti ṣubú lulẹ̀, mo gbọ́ ohùn kan tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu. Ó ní, ‘Saulu! Saulu! Kí ló dé tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi? O óo fara pa bí o bá ta igi ẹlẹ́gùn-ún nípàá.’
15. Mo wá bèèrè pé, ‘Ìwọ ta ni, Oluwa?’ Oluwa bá dáhùn ó ní, ‘Èmi ni Jesu tí ò ń ṣe inúnibíni sí.
16. Dìde nàró. Ohun tí mo fi farahàn ọ́ nìyí: mo ti yàn ọ́ láti jẹ́ iranṣẹ mi, kí o lè jẹ́rìí ohun tí o rí, ati ohun tí n óo fihàn ọ́.
17. N óo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli ati àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí n óo rán ọ sí.
18. Kí á lè là wọ́n lójú, kí á sì lè yí wọn pada láti inú òkùnkùn sinu ìmọ́lẹ̀, kí á lè gbà wọ́n lọ́wọ́ àṣẹ Satani, kí á sì fi wọ́n lé ọwọ́ Ọlọrun; kí wọ́n lè ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígbà mí gbọ́; kí wọ́n sì lè ní ogún pẹlu àwọn tí a ti yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun.’