1. Àwọn aposteli ati àwọn onigbagbọ yòókù tí ó wà ní Judia gbọ́ pé àwọn tí kì í ṣe Juu náà ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun.
2. Nígbà tí Peteru pada dé Jerusalẹmu, àwọn onigbagbọ tí ó jẹ́ Juu dá àríyànjiyàn sílẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà.
3. Wọ́n ní, “O wọlé tọ àwọn eniyan tí kò kọlà lọ, o sì bá wọn jẹun!”
4. Peteru bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ro gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wọn lẹ́sẹẹsẹ.
5. Ó ní, “Ìlú Jọpa ni mo wà tí mò ń gbadura, ni mo bá rí ìran kan. Nǹkankan tí ó dàbí aṣọ tí ó fẹ̀, tí wọ́n so ní igun mẹrin ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run títí ó fi dé ọ̀dọ̀ mi.
6. Mo tẹjú mọ́ ọn láti wo ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Mo bá rí àwọn ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹrin ati àwọn ẹranko ìgbẹ́ ati àwọn ẹranko tí ń fi àyà wọ́, ati àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run.
7. Mo wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó sọ fún mi pé, ‘Peteru, dìde, pa àwọn ẹran tí o bá fẹ́, kí o sì jẹ.’
8. Ṣugbọn mo ní, ‘Èèwọ̀, Oluwa! N kò jẹ ẹrankẹ́ran tabi ẹran àìmọ́ kan rí.’
9. Lẹẹkeji ohùn náà tún wá láti ọ̀run. Ó ní, ‘Ohunkohun tí Ọlọrun bá ti sọ di mímọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ pè é ní aláìmọ́ mọ́.’
10. Ẹẹmẹta ni ó ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ni nǹkankan bá tún fa gbogbo wọn pada sí ọ̀run.
11. Lákòókò náà gan-an ni àwọn ọkunrin mẹta tí a rán sí mi láti Kesaria dé ilé tí mo wà.
12. Ẹ̀mí wá sọ fún mi pé kí n bá wọn lọ láì kọminú. Mẹfa ninu àwọn arakunrin bá mi lọ. A bá wọ ilé ọkunrin náà.
13. Ó sọ fún wa bí òun ti ṣe rí angẹli tí ó dúró ninu ilé òun tí ó sọ pé, ‘Ranṣẹ lọ sí Jọpa, kí o pe Simoni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru wá.