15. Wọ́n kọ ìlànà rẹ̀, wọn kò pa majẹmu tí ó bá àwọn baba ńlá wọn dá mọ́, wọn kò sì fetí sí àwọn ìkìlọ̀ rẹ̀. Wọ́n ń sin oriṣa lásánlàsàn, àwọn pàápàá sì di eniyan lásán. Wọ́n tẹ̀ sí ìwà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká; wọ́n kọ òfin tí OLUWA ṣe fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà wọn.
16. Wọ́n rú gbogbo òfin OLUWA Ọlọrun wọn; wọ́n yá ère ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù meji, wọ́n ń sìn wọ́n. Wọ́n gbẹ́ ère oriṣa Aṣera, wọ́n sì ń bọ àwọn ohun tí ó wà lójú ọ̀run ati oriṣa Baali.
17. Wọ́n fi àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn rú ẹbọ sísun sí oriṣa, wọ́n ń ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn alásọtẹ́lẹ̀, wọ́n sì fi ara wọn jì láti ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n sì fi bẹ́ẹ̀ rú ibinu rẹ̀ sókè.
18. Nítorí náà, OLUWA bínú sí àwọn ọmọ Israẹli, ó sì run wọ́n kúrò níwájú rẹ̀, ṣugbọn ó fi Juda nìkan sílẹ̀.
19. Sibẹ, àwọn ará Juda kò pa òfin OLUWA Ọlọrun wọn mọ́, wọ́n tẹ̀lé ìwà tí àwọn ọmọ Israẹli ń hù.
20. OLUWA bá kọ gbogbo àwọn ìran Israẹli sílẹ̀, ó jẹ wọ́n níyà, ó sì fi wọ́n lé àwọn apanirun lọ́wọ́ títí wọ́n fi pa wọn run níwájú rẹ̀.
21. Lẹ́yìn tí OLUWA ti fi ìyapa sí ààrin Israẹli ati ìdílé Dafidi, Israẹli fi Jeroboamu ọmọ Nebati jọba. Jeroboamu mú kí wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, ó sì mú kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ ńlá.
22. Àwọn ọmọ Israẹli ń tẹ̀lé gbogbo ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, wọn kò sì yipada kúrò ninu wọn,
23. títí tí OLUWA fi run wọ́n kúrò níwájú rẹ̀, bí ó ti kìlọ̀ fún wọn láti ẹnu àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Asiria ṣe kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ìgbèkùn ní ilẹ̀ Asiria, níbi tí wọ́n wà títí di òní olónìí.
24. Ọba Asiria kó àwọn eniyan láti Babiloni, Kuta, Afa, Hamati ati Sefafaimu, ó kó wọn dà sinu àwọn ìlú Samaria dípò àwọn ọmọ Israẹli tí ó kó lọ. Wọ́n gba ilẹ̀ Samaria, wọ́n sì ń gbé inú àwọn ìlú rẹ̀.
25. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ dé ibẹ̀, wọn kò bẹ̀rù OLUWA, nítorí náà OLUWA rán àwọn kinniun sí ààrin wọn, wọ́n sì pa ninu àwọn eniyan tí ọba Asiria kó wá.
26. Wọ́n bá lọ ròyìn fún ọba Asiria pé àwọn eniyan tí ó kó lọ sí ilẹ̀ Samaria kò mọ òfin Ọlọrun ilẹ̀ náà, nítorí náà ni Ọlọrun ṣe rán kinniun tí ó ń pa wọ́n.
27. Ọba bá pàṣẹ, ó ní, “Ẹ dá ọ̀kan ninu àwọn alufaa tí a kó lẹ́rú pada sí Samaria, kí ó lè kọ́ àwọn eniyan náà ní òfin Ọlọrun ilẹ̀ náà.”
28. Nítorí náà, ọ̀kan ninu àwọn alufaa tí wọ́n kó wá láti Samaria pada lọ, ó sì ń gbé Bẹtẹli, níbẹ̀ ni ó ti ń kọ́ àwọn eniyan náà bí wọn yóo ṣe máa sin OLUWA.
29. Ṣugbọn àwọn oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè tí ń gbé Samaria ṣì ń gbẹ́ ère oriṣa wọn, wọ́n fi wọ́n sinu àwọn ilé oriṣa tí àwọn ọmọ Israẹli ti kọ́. Olukuluku wọn ṣe oriṣa tirẹ̀ sí ibi tí ó ń gbé.
30. Àwọn ará Babiloni gbẹ́ ère oriṣa Sukotu Benoti, àwọn ará Kuti gbẹ́ ère oriṣa Negali, àwọn ará Hamati gbẹ́ ère oriṣa Aṣima,
31. àwọn ará Afa gbẹ́ ère oriṣa Nibihasi ati Tataki, àwọn ará Sefafaimu sì ń sun ọmọ wọn ninu iná fún Adirameleki ati Anameleki, àwọn oriṣa wọn.