1. Ìbá wù mí kí o jẹ́ ọmọ ìyá mi ọkunrin,kí ó jẹ́ pé ọmú kan náà ni a jọ mú dàgbà.Bí mo bá pàdé rẹ níta,tí mo fẹnu kò ọ́ lẹ́nu,kì bá tí sí ẹni tí yóo fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.
2. Ǹ bá sìn ọ́ wá sílé ìyá mi,ninu ìyẹ̀wù ẹni tí ó tọ́ mi,ǹ bá fún ọ ní waini dídùn mu,àní omi èso Pomegiranate mi.
3. Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní ìgbèrí mi,kí o sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ fà mí mọ́ra!
4. Mo kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin obinrin Jerusalẹmu,pé ẹ kò gbọdọ̀ jí olùfẹ́ mi,títí tí yóo fi wù ú láti jí.
5. Ta ní ń bọ̀ láti inú aṣálẹ̀ yìí,tí ó fara ti olùfẹ́ rẹ̀?Lábẹ́ igi èso ápù ni mo ti jí ọ,níbi tí ìyá rẹ ti rọbí rẹ,níbi tí ẹni tí ó bí ọ ti rọbí.
6. Gbé mi lé oókan àyà rẹ bí èdìdì ìfẹ́,bí èdìdì, ní apá rẹ;nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú.Owú jíjẹ burú, àfi bí isà òkú.A máa jó bí iná,bí ọwọ́ iná tí ó lágbára.
7. Ọ̀pọ̀ omi kò lè pa iná ìfẹ́,ìgbì omi kò sì lè tẹ̀ ẹ́ rì.Bí eniyan bá gbìyànjú láti fi gbogbo nǹkan ìní rẹ̀ ra ìfẹ́,ẹ̀tẹ́ ni yóo fi gbà.
8. A ní àbúrò obinrin kékeré kan,tí kò lọ́mú.Kí ni kí á ṣe fún arabinrin wa náàní ọjọ́ tí wọ́n bá wá tọrọ rẹ̀?
9. Bí ó bá jẹ pé ògiri ni arabinrin wa,à óo mọ ilé-ìṣọ́ fadaka lé e lórí.Bí ó bá jẹ́ pé ìlẹ̀kùn ni,pákó Kedari ni a óo fi yí i ká.
10. Ògiri ni mí,ọmú mi sì dàbí ilé-ìṣọ́;ní ojú olùfẹ́ mi,mo ní alaafia ati ìtẹ́lọ́rùn.