Ìbá wù mí kí o jẹ́ ọmọ ìyá mi ọkunrin,kí ó jẹ́ pé ọmú kan náà ni a jọ mú dàgbà.Bí mo bá pàdé rẹ níta,tí mo fẹnu kò ọ́ lẹ́nu,kì bá tí sí ẹni tí yóo fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.