7. Ó sọ fún un pé “Èmi ni OLUWA tí ó mú ọ jáde láti ìlú Uri, ní ilẹ̀ Kalidea, láti fi ilẹ̀ yìí fún ọ ní ohun ìní.”
8. Ṣugbọn Abramu bèèrè pé, “OLUWA Ọlọrun, báwo ni n óo ṣe mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóo jẹ́ tèmi?”
9. OLUWA dá a lóhùn, ó ní, “Mú ẹgbọ̀rọ̀ abo mààlúù ọlọ́dún mẹta kan, ati ewúrẹ́ ọlọ́dún mẹta kan, ati àgbò ọlọ́dún mẹta kan, ati àdàbà kan ati ọmọ ẹyẹlé kan wá.”
10. Ó kó gbogbo wọn wá fún OLUWA, ó là wọ́n sí meji meji, ó sì tẹ́ wọn sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn lọ, ṣugbọn kò la àdàbà ati ẹyẹlé náà.
11. Nígbà tí àwọn ẹyẹ tí wọ́n máa ń jẹ òkú ẹran rábàbà wá sí ibi tí Abramu to àwọn ẹran náà sí, ó lé wọn.
12. Nígbà tí oòrùn ń wọ̀ lọ, oorun bẹ̀rẹ̀ sí kun Abramu, ó sì sun àsùnwọra, jìnnìjìnnì mú un, òkùnkùn biribiri sì bò ó mọ́lẹ̀.
13. Nígbà náà ni OLUWA sọ fún un pé, “Mọ̀ dájúdájú pé àwọn ọmọ rẹ yóo lọ gbé ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn, wọn yóo di ẹrú níbẹ̀, àwọn ará ibẹ̀ yóo sì mú wọn sìn fún irinwo (400) ọdún.
14. Ṣugbọn n óo mú ìdájọ́ wá sórí orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóo sìn. Àṣẹ̀yìnwá, àṣẹ̀yìnbọ̀, wọn yóo jáde kúrò níbẹ̀ pẹlu ọpọlọpọ dúkìá.