1. Solomoni gbé ọmọ Farao, ọba Ijipti níyàwó, ó fi bá ọba Farao dá majẹmu àjọṣepọ̀ láàrin wọn. Solomoni mú iyawo náà wá sí ìlú Dafidi títí tí ó fi parí ààfin rẹ̀ ati ilé OLUWA tí ó ń kọ́, ati odi Jerusalẹmu tí ó ń mọ lọ́wọ́.
2. Oríṣìíríṣìí pẹpẹ ìrúbọ ni àwọn eniyan tẹ́ káàkiri, tí wọ́n sì ń rúbọ lórí wọn, nítorí wọn kò tí ì kọ́ ilé OLUWA nígbà náà.
3. Solomoni fẹ́ràn OLUWA, ó sì ń tẹ̀lé ìlànà Dafidi, baba rẹ̀, ṣugbọn òun náà a máa rúbọ, a sì máa sun turari lórí àwọn pẹpẹ ìrúbọ.
4. Ọba a máa lọ sí Gibeoni láti rúbọ, nítorí pé níbẹ̀ ni pẹpẹ tí ó lókìkí jùlọ nígbà náà wà. A máa fi ẹgbẹrun (1,000) ẹran rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ náà.
5. OLUWA fara han Solomoni ní ojú àlá ní òru ọjọ́ kan ní Gibeoni, ó sì bi í pé, “Kí ni o fẹ́ kí n fún ọ?”
6. Solomoni dá OLUWA lóhùn, ó ní: “O ti fi ìfẹ́ ńlá rẹ, tí kìí yẹ̀ hàn sí Dafidi, baba mi, iranṣẹ rẹ, nítorí pé ó bá ọ lò pẹlu òtítọ́, òdodo ati ọkàn dídúró ṣinṣin. O sì ti fi ìfẹ́ ńlá tí kì í yẹ̀ yìí hàn sí i, o fún un ní ọmọ tí ó jọba lẹ́yìn rẹ̀ lónìí.
7. Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun mi, ìwọ ni o jẹ́ kí èmi iranṣẹ rẹ gun orí oyè lẹ́yìn baba mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọde ni mí, n kò sì mọ̀ bí wọ́n ti ń ṣe àkóso.
8. O sì fi èmi iranṣẹ rẹ sí ààrin àwọn eniyan tí o ti yàn fún ara rẹ, àwọn tí wọ́n pọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò lóǹkà.
9. Nítorí náà, OLUWA, fún èmi iranṣẹ rẹ ní ọgbọ́n láti darí àwọn eniyan rẹ, kí n lè mọ ìyàtọ̀ láàrin ire ati ibi, nítorí pé, bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ta ni lè ṣe àkóso àwọn eniyan rẹ tí wọ́n pọ̀ báyìí?”
10. Inú OLUWA dùn fún ohun tí Solomoni bèèrè.
11. Ọlọrun sì dá a lóhùn, ó ní, “Nítorí pé ọgbọ́n láti mọ ohun tí ó dára ni o bèèrè, tí o kò bèèrè ẹ̀mí gígùn, tabi ọpọlọpọ ọrọ̀ fún ara rẹ, tabi ẹ̀mí àwọn ọ̀tá rẹ,
12. wò ó! N óo fún ọ ní ohun tí o bèèrè. Ọgbọ́n ati òye tí n óo fún ọ yóo tayọ ti gbogbo àwọn aṣiwaju rẹ, ati ti àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ.
13. N óo fún ọ ní ohun tí o kò tilẹ̀ bèèrè. O óo ní ọrọ̀ ati ọlá tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní sí ọba kan tí yóo dàbí rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
14. Bí o bá ń gbọ́ tèmi, tí o sì ń pa gbogbo àwọn òfin, ati àwọn ìlànà mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí Dafidi, baba rẹ ti ṣe, n óo fún ọ ní ẹ̀mí gígùn pẹlu.”