Solomoni ọba bá pàṣẹ fún Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, pé kí ó lọ pa Ṣimei; Bẹnaya bá jáde lọ, ó sì pa á. Lẹ́yìn náà ni gbogbo ìjọba Solomoni ọba wá wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.