Iṣe Apo 24:13-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Bẹ̃ni nwọn kò le ladi ohun ti nwọn fi mi sùn si nisisiyi.

14. Ṣugbọn eyi ni mo jẹwọ fun ọ, pe bi Ọna ti a npè ni adamọ̀, bẹ̃li emi nsìn Ọlọrun awọn baba wa, emi ngbà nkan gbogbo gbọ́ gẹgẹ bi ofin, ati ti a kọ sinu iwe awọn woli:

15. Mo si ni ireti sipa ti Ọlọrun, eyi ti awọn tikarawọn pẹlu jẹwọ, pe ajinde okú mbọ̀, ati ti olõtọ, ati ti alaiṣõtọ.

16. Ninu eyi li emi si nṣe idaraya, lati ni ẹri-ọkàn ti kò li ẹ̀ṣẹ sipa ti Ọlọrun, ati si enia nigbagbogbo.

17. Ṣugbọn lẹhin ọdún pipọ, mo mu ọrẹ-ãnu fun orilẹ-ède mi wá, ati ọrẹ-ẹbọ.

18. Larin wọnyi ni nwọn ri mi ni iwẹnu ni tẹmpili, bẹ̃ni kì iṣe pẹlu awujọ, tabi pẹlu ariwo.

19. Ṣugbọn awọn Ju lati Asia wà nibẹ, awọn ti iba wà nihinyi niwaju rẹ, ki nwọn ki o já mi ni koro, bi nwọn ba li ohunkohun si mi.

20. Bi kò ṣe bẹ̃, jẹ ki awọn enia wọnyi tikarawọn sọ iṣe buburu ti nwọn ri lọwọ mi, nigbati mo duro niwaju ajọ igbimọ yi,

21. Bikoṣe ti gbolohùn kan yi, ti mo ke nigbati mo duro li ãrin wọn, Nitori ajinde okú li a ṣe ba mi wijọ lọdọ nyin loni yi.

22. Nigbati Feliksi gbọ́ nkan wọnyi, oye sa ye e li ayetan nipa Ọna na; o tú wọn ká na, o ni, Nigbati Lisia olori ogun ba sọkalẹ wá, emi o wadi ọ̀ran nyin daju.

23. O si paṣẹ fun balogun ọrún kan pe, ki o mã ṣe itọju Paulu, ki o si bùn u làye, ati pe ki o máṣe dá awọn ojulumọ̀ rẹ̀ lẹkun, lati ma ṣe iranṣẹ fun u.

24. Ṣugbọn lẹhin ijọ melokan, Feliksi de ti on ti Drusilla obinrin rẹ̀, ti iṣe Ju, o si ranṣẹ pè Paulu, o si gbọ́ ọ̀rọ lọdọ rẹ̀ nipa igbagbọ́ ninu Kristi Jesu.

25. Bi o si ti nsọ asọye nipa ti ododo ati airekọja ati idajọ ti mbọ̀, ẹ̀ru ba Feliksi, o dahùn wipe, Mã lọ nisisiyi na; nigbati mo ba si ni akokò ti o wọ̀, emi o ranṣẹ pè ọ.

26. O si nreti pẹlu pe a ba fun on li owo lati ọwọ́ Paulu wá, ki on ki o le da a silẹ: nitorina a si ma ranṣẹ si i nigbakugba, a ma ba a sọ̀rọ.

27. Ṣugbọn lẹhin ọdún meji, Porkiu Festu rọpò Feliksi: Feliksi si nfẹ ṣe oju're fun awọn Ju, o fi Paulu silẹ li ondè.

Iṣe Apo 24