6. O si ṣe, bi emi ti nlọ, ti mo si sunmọ eti Damasku niwọn ọjọkanri, li ojijì, imọlẹ nla mọ́ ti ọrun wá yi mi ká.
7. Mo si ṣubu lùlẹ, mo si ngbọ́ ohùn kan ti o wi fun mi pe, Saulu, Saulu, ẽṣe ti iwọ fi nṣe inunibini si mi?
8. Emi si dahùn wipe, Iwọ tani, Oluwa? O si wi fun mi pe, Emi Jesu ti Nasareti ni, ẹniti iwọ nṣe inunibini si.
9. Awọn ti o si wà pẹlu mi ri imọlẹ na nitõtọ, ẹ̀ru si ba wọn; ṣugbọn nwọn kò gbọ́ ohùn ẹniti mba mi sọrọ.
10. Mo si wipe, Kini ki emi ki o ṣe, Oluwa? Oluwa si wi fun mi pe, Dide, ki o si lọ si Damasku; nibẹ̀ li a o si sọ ohun gbogbo fun ọ ti a yàn fun ọ lati ṣe.
11. Bi emi kò si ti le riran nitori itànṣan imọlẹ na, a ti ọwọ́ awọn ti o wà lọdọ mi fà mi, mo si de Damasku.
12. Ẹnikan si tọ̀ mi wá, Anania, ọkunrin olufọkansìn gẹgẹ bi ofin, ti o li orukọ rere lọdọ gbogbo awọn Ju ti o ngbe ibẹ̀.
13. O si duro tì mi, o si wi fun mi pe, Saulu arakunrin, riran. Ni wakati kanna mo si ṣiju soke wò o.
14. O si wipe, Ọlọrun awọn baba wa yàn ọ, lati mọ̀ ifẹ rẹ̀, ati lati ri Olõtọ nì, ati lati gbọ́ ohùn li ẹnu rẹ̀,
15. Ki iwọ ki o le ṣe ẹlẹri rẹ̀ fun gbogbo enia, li ohun ti iwọ ti ri ti iwọ si ti gbọ́.
16. Njẹ nisisiyi kini iwọ nduro de? Dide, ki a si baptisi rẹ, ki o si wẹ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ nù, ki o si mã pè orukọ Oluwa.
17. O si ṣe pe, nigbati mo pada wá si Jerusalemu, ti mo ngbadura ni tẹmpili mo bọ si ojuran;
18. Mo si ri i, o wi fun mi pe, Yara, ki o si jade kuro ni Jerusalemu kánkán: nitori nwọn kì yio gbà ẹrí rẹ nipa mi.
19. Emi si wipe, Oluwa, awọn pãpã mọ̀ pe, emi a ti mã sọ awọn ti o gbà ọ gbọ sinu tubu, emi a si mã lù wọn ninu sinagogu gbogbo:
20. Nigbati a si ta ẹ̀jẹ Stefanu ẹlẹri rẹ silẹ, emi na pẹlu duro nibẹ̀, mo si li ohùn si ikú rẹ̀, mo si nṣe itọju aṣọ awọn ẹniti o pa a.
21. O si wi fun mi pe, Mã lọ: nitori emi ó rán ọ si awọn Keferi lokere réré.