12. Bí Hana ti ń gbadura sí OLUWA, Eli ń wo ẹnu rẹ̀.
13. Hana ń gbadura ninu ọkàn rẹ̀, kìkì ètè rẹ̀ nìkan ní ń mì, ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ohun tí ó ń sọ. Nítorí náà, Eli rò pé ó ti mu ọtí yó ni.
14. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí pé, “O óo ti mu ọtí waini pẹ́ tó? Sinmi ọtí mímu.”
15. Hana dá a lóhùn, pé, “Rárá o, oluwa mi, n kò fẹnu kan ọtí waini tabi ọtí líle. Ìbànújẹ́ ló bá mi, tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi ń gbadura, tí mo sì ń tú ọkàn mi jáde fún OLUWA.
16. Má rò pé ọ̀kan ninu àwọn oníranù obinrin ni mí. Ninu ìbànújẹ́ ńlá ati àníyàn ni mò ń gbadura yìí.”
17. Eli bá dá a lóhùn, ó ní, “Máa lọ ní alaafia, Ọlọrun Israẹli yóo fún ọ ní ohun tí ò ń tọrọ lọ́wọ́ rẹ̀.”
18. Hana bá dá a lóhùn pé, “Jẹ́ kí èmi, iranṣẹbinrin rẹ, bá ojurere rẹ pàdé.” Ó bá dìde, ó jẹun, ó dárayá, kò sì banújẹ́ mọ́.
19. Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, Elikana ati ìdílé rẹ̀ múra, wọ́n sì sin OLUWA. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbéra, wọ́n pada sí ilé wọn, ní Rama. Nígbà tí ó yá, Elikana bá Hana lòpọ̀, OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀.
20. Hana lóyún, ó bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọmọ náà ní Samuẹli, ó ní, “Títọrọ ni mo tọrọ rẹ̀ lọ́wọ́ OLUWA.”
21. Nígbà tí ó yá, àkókò tó fún Elikana ati ìdílé rẹ̀ láti lọ sí Ṣilo, láti lọ rú ẹbọ ọdọọdún, kí Elikana sì san ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́ fún OLUWA.
22. Ṣugbọn Hana kò bá wọn lọ. Ó wí fún ọkọ rẹ̀ pé, “Bí mo bá ti gba ọmú lẹ́nu ọmọ yìí ni n óo mú un lọ sí ilé OLUWA, níbẹ̀ ni yóo sì máa gbé títí ọjọ́ ayé rẹ̀.”
23. Elikana dá a lóhùn pé, “Ṣe bí ó bá ti tọ́ ní ojú rẹ. Dúró ní ilé, títí tí o óo fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀. Kí OLUWA jẹ́ kí o lè mú ìlérí rẹ ṣẹ.” Hana bá dúró ní ilé, ó ń tọ́jú ọmọ náà.
24. Nígbà tí ó gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, ó mú un lọ́wọ́ lọ sí Ṣilo. Nígbà tí ó ń lọ, ó mú akọ mààlúù ọlọ́dún mẹta kan lọ́wọ́, ati ìyẹ̀fun ìwọ̀n efa kan, ati ọtí waini ẹ̀kún ìgò aláwọ kan. Ó sì mú Samuẹli lọ sí Ṣilo ní ilé OLUWA, ọmọde ni Samuẹli nígbà náà.