16. Tamari dá a lóhùn pé, “Rárá, arakunrin mi, lílé tí ò ń lé mi jáde yìí burú ju ipá tí o fi bá mi lòpọ̀ lọ.”Ṣugbọn Amnoni kọ̀, kò gbọ́ tirẹ̀.
17. Kàkà bẹ́ẹ̀, Amnoni pe iranṣẹ rẹ̀ kan, ó wí fún un pé, “Mú obinrin yìí jáde kúrò níwájú mi, tì í sóde, kí o sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.”
18. Iranṣẹ náà bá ti Tamari jáde, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.Aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ alápá gígùn, irú èyí tí àwọn ọmọ ọba, obinrin, tí kò tíì wọlé ọkọ máa ń wọ̀, ni Tamari wọ̀.
19. Tamari bá ku eérú sí orí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó káwọ́ lórí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún bí ó ti ń lọ.
20. Nígbà tí Absalomu, ẹ̀gbọ́n Tamari, rí i, ó bi í léèrè pé, “Ṣé Amnoni bá ọ lòpọ̀ ni? Jọ̀wọ́, arabinrin mi, gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, ọmọ baba kan náà ni ẹ̀yin mejeeji, nítorí náà, má sọ fún ẹnikẹ́ni.” Tamari bá ń gbé ilé Absalomu. Òun nìkan ni ó dá wà, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ pupọ.
21. Nígbà tí Dafidi ọba gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí i gidi.
22. Absalomu kórìíra Amnoni gan-an nítorí pé ó fi ipá bá Tamari, àbúrò rẹ̀, lòpọ̀, ṣugbọn kò bá a sọ nǹkankan; ìbáà ṣe rere ìbáà sì ṣe burúkú.
23. Lẹ́yìn ọdún meji tí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀, Absalomu lọ rẹ́ irun aguntan rẹ̀ ní Baali Hasori, lẹ́bàá ìlú Efuraimu, ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba patapata lọkunrin sibẹ.
24. Ó lọ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ọba, ó wí fún un pé, “Kabiyesi, iranṣẹ rẹ ń rẹ́ irun aguntan rẹ̀, mo sì fẹ́ kí kabiyesi ati gbogbo àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá síbi àjọ̀dún náà.”
25. Ọba ní, “Rárá, ọmọ mi, bí gbogbo wa bá lọ, wahala náà yóo pọ̀jù fún ọ.” Absalomu rọ ọba títí, ṣugbọn ó kọ̀ jálẹ̀. Ọba bá súre fún un, ó ní kí ó máa lọ.
26. Absalomu dáhùn pé, “Ó dára, bí o kò bá lè lọ, ṣé o óo jẹ́ kí Amnoni arakunrin mi lọ?”Ọba bá bèèrè pé, “Nítorí kí ni yóo ṣe ba yín lọ?”
27. Ṣugbọn Absalomu rọ Dafidi títí tí ó fi gbà pé kí Amnoni ati àwọn ọmọ ọba yòókù lọkunrin bá a lọ.Absalomu sì se àsè rẹpẹtẹ, bí ẹni pé ọba ni ó fẹ́ ṣe lálejò.
28. Absalomu wí fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ máa kíyèsí Amnoni, nígbà tí ó bá mu ọtí yó, bí mo bá ti fun yín ní àṣẹ pé kí ẹ pa á, pípa ni kí ẹ pa á, ẹ má bẹ̀rù; èmi ni mo ran yín. Ẹ mú ọkàn gírí kí ẹ sì ṣe bí akikanju.”
29. Àwọn iranṣẹ náà bá tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀, wọ́n sì pa Amnoni. Gbogbo àwọn ọmọ Dafidi yòókù bá gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, wọ́n sì sá lọ.
30. Nígbà tí wọn ń sá bọ̀ wálé, àwọn kan wá sọ fún Dafidi pé, “Absalomu ti pa gbogbo àwọn ọmọ rẹ, ati pé kò ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan.”
31. Ọba dìde, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó sì sùn sórí ilẹ̀ lásán, àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ fa aṣọ tiwọn náà ya.
32. Ṣugbọn Jonadabu, ọmọ Ṣimea, arakunrin Dafidi, wí fún ọba pé, “Kabiyesi, ẹnikẹ́ni kò pa gbogbo àwọn ọmọ rẹ. Amnoni nìkan ni Absalomu pàṣẹ pé kí wọ́n pa. Láti ìgbà tí Amnoni ti fi ipá bá Tamari, arabinrin rẹ̀ lòpọ̀, ni ó ti pinnu láti ṣe ohun tí ó ṣe yìí.
33. Nítorí náà, kí oluwa mi má gba ìròyìn tí wọ́n mú wá gbọ́, pé gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n ti kú. Amnoni nìkan ni wọ́n pa.”
34. Absalomu sá lọ ní àkókò yìí.Kò pẹ́ rárá, lẹ́yìn náà, ọmọ ogun tí ń ṣọ́ ọ̀nà tí ó wọ ìlú rí ogunlọ́gọ̀ eniyan, wọ́n ń bọ̀ láti ọ̀nà Horonaimu, lẹ́bàá òkè.