17. Ọlọrun, láti ìgbà èwe mi ni o ti kọ́ mi,títí di òní ni mo sì ń polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ,
18. Nisinsinyii tí mo ti dàgbà, tí ewú sì ti gba orí mi,Ọlọrun, má kọ̀ mí sílẹ̀,títí tí n óo fi ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ,àní, iṣẹ́ agbára rẹ, fún gbogbo àwọn ìran tí ń bọ̀.
19. Ọlọrun, iṣẹ́ òdodo rẹ kan ojú ọ̀run,ìwọ tí o ṣe nǹkan ńlá,Ọlọrun, ta ni ó dàbí rẹ?
20. O ti jẹ́ kí n rí ọpọlọpọ ìpọ́njú ńlá,ṣugbọn óo tún mú ìgbé ayé mi pada bọ̀ sípò;óo tún ti gbé mi dìde láti inú isà òkú.
21. O óo fi kún ọlá mi,o óo sì tún tù mí ninu.
22. Èmi náà óo máa fi hapu yìn ọ́,nítorí òtítọ́ rẹ, Ọlọrun mi;n óo máa fi ohun èlò orin yìn ọ́,ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.
23. N óo máa kígbe fún ayọ̀,nígbà tí mo bá ń kọ orin ìyìn sí ọ;ẹ̀mí mi tí o ti kó yọ, yóo ké igbe ayọ̀.
24. Ẹnu mi yóo ròyìn iṣẹ́ rẹ tọ̀sán-tòru,nítorí a ti ṣẹgun àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára,a sì ti dójú tì wọ́n.