Jẹnẹsisi 40:15-23 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Nítorí pé jíjí ni wọ́n jí mi gbé kúrò ní ilẹ̀ Heberu, ati pé níhìn-ín gan-an, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ tí wọ́n fi gbé mi jù sẹ́wọ̀n yìí.”

16. Alásè rí i pé ìtumọ̀ rẹ̀ dára, ó wí fún Josẹfu pé, “Èmi náà lá àlá kan, mo ru agbọ̀n àkàrà mẹta lórí, lójú àlá.

17. Mo rí i pé oríṣìíríṣìí oúnjẹ Farao ni ó wà ninu agbọ̀n tí ó wà ní òkè patapata, mo bá tún rí i tí àwọn ẹyẹ bẹ̀rẹ̀ sí jẹ àwọn oúnjẹ yìí ní orí mi.”

18. Josẹfu dáhùn, ó ní, “Ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: àwọn agbọ̀n mẹta náà dúró fún ọjọ́ mẹta.

19. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta, Farao ọba yóo yọ ọ́ jáde níhìn-ín, yóo bẹ́ ọ lórí, yóo gbé ọ kọ́ igi, àwọn ẹyẹ yóo sì jẹ ẹran ara rẹ.”

20. Ní ọjọ́ kẹta tíí ṣe ọjọ́ ìbí Farao, ọba se àsè ńlá fún gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì mú agbọ́tí rẹ̀ ati alásè rẹ̀ jáde sí ààrin àwọn iranṣẹ rẹ̀.

21. Ó dá agbọ́tí pada sí ipò rẹ̀ láti máa gbé ọtí fún un,

22. ṣugbọn ó pàṣẹ kí wọ́n lọ so olórí alásè kọ́ igi, gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti túmọ̀ àlá wọn fún wọn.

23. Ṣugbọn olórí agbọ́tí kò ranti Josẹfu mọ, ó gbàgbé rẹ̀ patapata.

Jẹnẹsisi 40