Jẹnẹsisi 3:7-15 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ojú àwọn mejeeji bá là, wọ́n sì mọ̀ pé ìhòòhò ni àwọn wà, wọ́n bá gán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sán an mọ́ ìdí.

8. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbúròó OLUWA Ọlọrun tí ń rìn ninu ọgbà. Wọ́n bá sá pamọ́ sí ààrin àwọn igi ọgbà.

9. Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun pe ọkunrin náà, ó bi í pé, “Níbo ni o wà?”

10. Ó dá Ọlọrun lóhùn, ó ní, “Nígbà tí mo gbúròó rẹ ninu ọgbà, ẹ̀rù bà mí, mo bá farapamọ́ nítorí pé ìhòòhò ni mo wà.”

11. Ọlọrun bi í pé, “Ta ló sọ fún ọ pé ìhòòhò ni o wà? Àbí o ti jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ?”

12. Ọkunrin náà dáhùn, ó ní, “Obinrin tí o fi tì mí ni ó fún mi ninu èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.”

13. OLUWA Ọlọrun bi obinrin náà pé, “Irú kí ni o dánwò yìí?” Obinrin náà dáhùn, ó ní, “Ejò ni ó tàn mí tí mo fi jẹ ẹ́.”

14. OLUWA Ọlọrun bá sọ fún ejò náà pé,“Nítorí ohun tí o ṣe yìí,o di ẹni ìfibú jùlọ láàrin gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn ati àwọn ẹranko.Àyà rẹ ni o óo máa fi wọ́ káàkiri,erùpẹ̀ ni o óo sì máa jẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

15. N óo dá ọ̀tá sí ààrin ìwọ ati obinrin náà,ati sí ààrin atọmọdọmọ rẹ ati atọmọdọmọ rẹ̀.Wọn óo máa fọ́ ọ lórí,ìwọ náà óo sì máa bù wọ́n ní gìgísẹ̀ jẹ.”

Jẹnẹsisi 3