20. Jakọbu bá sin Labani fún ọdún meje nítorí Rakẹli, ó sì dàbí ọjọ́ mélòó kan lójú rẹ̀ nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí Rakẹli.
21. Nígbà tí ó yá, Jakọbu sọ fún Labani pé, “Fún mi ní aya mi, kí á lè ṣe igbeyawo, nítorí ọjọ́ ti pé.”
22. Labani bá pe gbogbo àwọn ọkunrin ibẹ̀ jọ, ó se àsè ńlá fún wọn.
23. Ṣugbọn nígbà tí ó di àṣáálẹ́, Lea ni wọ́n mú wá fún Jakọbu dípò Rakẹli, Jakọbu sì bá a lòpọ̀.
24. Labani fi Silipa ẹrubinrin rẹ̀ fún Lea pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún un.
25. Nígbà tí ó di òwúrọ̀, Jakọbu rí i pé Lea ni wọ́n mú wá fún òun. Ó bi Labani, ó ní, “Irú kí ni o ṣe sí mi yìí? Ṣebí nítorí Rakẹli ni mo fi sìn ọ́? Èéṣe tí o tàn mí jẹ?”
26. Labani dáhùn, ó ní, “Ní ilẹ̀ tiwa níhìn-ín, àwa kì í fi àbúrò fọ́kọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n.
27. Fara balẹ̀ parí àwọn ètò ọ̀sẹ̀ igbeyawo ti eléyìí, n óo sì fún ọ ní ekeji náà, ṣugbọn o óo tún sìn mí ní ọdún meje sí i.”
28. Jakọbu gbà bẹ́ẹ̀, ó ṣe ọ̀sẹ̀ igbeyawo Lea parí, lẹ́yìn náà Labani fa Rakẹli, ọmọ rẹ̀ fún un.
29. Labani fi Biliha, ẹrubinrin rẹ̀ fún Rakẹli, ọmọbinrin rẹ̀, pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún un.
30. Jakọbu bá Rakẹli náà lòpọ̀, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ ju Lea lọ, ó sì sin Labani fún ọdún meje sí i.