Ìṣe Àwọn Aposteli 16:5-14 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ túbọ̀ ń lágbára sí i ninu igbagbọ, tí wọ́n sì ń pọ̀ sí i ní iye lojoojumọ.

6. Wọ́n gba ilẹ̀ Firigia ati Galatia kọjá. Ẹ̀mí Mímọ́ kò gbà wọ́n láàyè láti lọ waasu ọ̀rọ̀ Oluwa ní Esia.

7. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Misia, wọ́n gbìyànjú láti lọ sí Bitinia. Ṣugbọn Ẹ̀mí Jesu kò gbà fún wọn.

8. Nígbà tí wọ́n ti la Misia kọjá, wọ́n dé Tiroasi.

9. Nígbà tí ó di alẹ́, Paulu rí ìran kan. Ó rí ọkunrin kan ará Masedonia tí ó dúró, tí ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Sọdá sí Masedonia níbí kí o wá ràn wá lọ́wọ́.”

10. Gbàrà tí ó rí ìran náà, a wá ọ̀nà láti lọ sí Masedonia; a pinnu pé Ọlọrun ni ó pè wá láti lọ waasu fún wọn níbẹ̀.

11. Nígbà tí a wọ ọkọ̀ láti Tiroasi, a lọ tààrà sí Samotirake. Ní ọjọ́ keji a gúnlẹ̀ ní Neapoli.

12. Láti ibẹ̀, a lọ sí Filipi tíí ṣe olú-ìlú ilẹ̀ Masedonia. Àwọn ará Romu ni wọ́n tẹ ìlú yìí dó. A bá wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan.

13. Ní Ọjọ́ Ìsinmi a jáde lọ sẹ́yìn odi ìlú lẹ́bàá odò, níbi tí a rò pé a óo ti rí ibi tí wọn máa ń gbadura. A bá jókòó, a bá àwọn obinrin tí ó péjọ níbẹ̀ sọ̀rọ̀.

14. Obinrin kan wà níbẹ̀ tí ó ń jẹ́ Lidia, ará Tiatira, tí ó ń ta aṣọ àlàárì. Ó jẹ́ ẹnìkan tí ó ń sin Ọlọrun. Ó fetí sílẹ̀, Ọlọrun ṣí i lọ́kàn láti gba ohun tí Paulu ń sọ.

Ìṣe Àwọn Aposteli 16