18. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò tún ní ìkọminú mọ́ nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Wọ́n bá ń yin Ọlọrun. Wọ́n ní, “Èyí ni pé Ọlọrun ti fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù náà ní anfaani láti ronupiwada kí wọ́n lè ní ìyè.”
19. Àwọn tí ó túká nígbà inúnibíni tí ó ṣẹlẹ̀ ní àkókò Stefanu dé Fonike ní Kipru ati Antioku. Wọn kò bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ ìyìn rere àfi àwọn Juu nìkan.
20. Ṣugbọn nígbà tí àwọn kan ninu àwọn ará Kipru ati Kirene dé Antioku, wọ́n bá àwọn ará Giriki sọ̀rọ̀, wọ́n ń waasu Oluwa Jesu fún wọn.
21. Agbára Oluwa hàn ninu iṣẹ́ wọn. Ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n gbàgbọ́, tí wọ́n sì yipada sí Oluwa.
22. Ìròyìn dé etí ìjọ tí ó wà ní Jerusalẹmu nípa wọn. Wọ́n bá rán Banaba sí Antioku.
23. Nígbà tí ó dé, tí ó rí bí Ọlọrun ti ṣiṣẹ́ láàrin wọn, inú rẹ̀ dùn. Ó gba gbogbo wọn níyànjú pé kí wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn dúró ti Oluwa pẹlu òtítọ́.
24. Nítorí Banaba jẹ́ eniyan rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, tí ó sì gbàgbọ́ tọkàntọkàn, ọ̀pọ̀ eniyan ni ó di onigbagbọ.
25. Banaba bá wá Paulu lọ sí Tasu.