1. NIGBANA li olori alufa wipe, Nkan wọnyi ha ri bẹ̃ bi?
2. On si wipe, Alàgba, ará, ati baba, ẹ fetisilẹ̀; Ọlọrun ogo fi ara hàn fun Abrahamu baba wa, nigbati o wà ni Mesopotamia, ki o to ṣe atipo ni Harani,
3. O si wi fun u pe, Jade kuro ni ilẹ rẹ, ati lọdọ awọn ibatan rẹ, ki o si wá si ilẹ ti emi ó fi hàn ọ.
4. Nigbana li o jade kuro ni ilẹ awọn ara Kaldea, o si ṣe atipo ni Harani: lẹhin igbati baba rẹ̀ kú, Ọlọrun mu u ṣipo pada wá si ilẹ yi, nibiti ẹnyin ngbé nisisiyi.
5. Kò si fun u ni ini kan, ani to bi ẹsẹ ilẹ kan; ṣugbọn o leri pe, on ó fi i fun u ni ilẹ-nini, ati fun awọn irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀, nigbati kò ti ili ọmọ.
6. Ọlọrun si sọ bayi pe, irú-ọmọ rẹ̀ yio ṣe atipo ni ilẹ àjeji; nwọn ó si sọ wọn di ẹru, nwọn o si pọ́n wọn loju ni irinwo ọdún.
7. Ọlọrun wipe, Orilẹ-ède na ti nwọn o ṣe ẹrú fun, li emi ó da lẹjọ: lẹhin na ni nwọn o si jade kuro, nwọn o si wá sìn mi nihinyi.
8. O si fun u ni majẹmu ikọlà: bẹ̃li Abrahamu bí Isaaki, o kọ ọ ni ilà ni ijọ kẹjọ; Isaaki si bí Jakọbu; Jakọbu si bi awọn baba nla mejila.
9. Awọn baba nla si ṣe ilara Josefu, nwọn si tà a si Egipti: ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.
10. O si yọ ọ kuro ninu ipọnju rẹ̀ gbogbo, o si fun u li ojurere ati ọgbọ́n li oju Farao ọba Egipti; on si fi i jẹ bãlẹ Egipti ati gbogbo ile rẹ̀.
11. Iyan kan si wá imu ni gbogbo ilẹ Egipti ati ni Kenaani, ati ipọnju pipọ: awọn baba wa kò si ri onjẹ.
12. Ṣugbọn nigbati Jakọbu gbọ́ pe alikama mbẹ ni Egipti, o rán awọn baba wa lọ lẹrinkini.