5. On si gbọ̀n ẹranko na sinu iná, ohunkohun kan kò ṣe e.
6. Ṣugbọn nwọn nwoye igbati yio wú, tabi ti yio si ṣubu lulẹ kú lojiji: nigbati nwọn wò titi, ti nwọn kò si ri nkankan ki o ṣe e, nwọn pa iyè da pe, oriṣa kan li ọkunrin yi.
7. Li àgbegbe ibẹ̀ ni ilẹ ọkunrin ọlọlá erekuṣu na wà, orukọ ẹniti a npè ni Publiu; ẹniti o gbà wa si ọdọ, ti o si fi inu rere mu wa wọ̀ ni ijọ mẹta.
8. O si ṣe, baba Publiu dubulẹ arùn ibà ati ọ̀rin: ẹniti Paulu wọle tọ̀ lọ, ti o si gbadura fun, nigbati o si fi ọwọ́ le e, o mu u larada.
9. Nigbati eyi si ṣe tan, awọn iyokù ti o li arùn li erekuṣu na, tọ̀ ọ wá, o si mu wọn larada:
10. Awọn ẹniti o bù ọlá pipọ fun wa; nigbati awa si nlọ, nwọn dì nkan gbogbo rù wa ti a ba ṣe alaini.
11. Ati lẹhin oṣù mẹta awa wọ̀ ọkọ Aleksandria kan, ti o lo akoko otutu li erekuṣu na, àmi eyi ti iṣe Kastoru on Poluksu.
12. Nigbati awa gúnlẹ ni Sirakuse, awa gbé ibẹ̀ ni ijọ mẹta.
13. Lati ibẹ̀ nigbati awa lọ yiká, awa de Regioni: ati lẹhin ijọ kan afẹfẹ gusù dide, ni ijọ keji rẹ̀ awa si de Puteoli,
14. Nibiti a gbé ri awọn arakunrin, ti nwọn si bẹ̀ wa lati ba wọn gbé ni ijọ meje: bẹ̃li awa si lọ si ìha Romu.
15. Ati lati ibẹ nigbati awọn arakunrin gburó wa, nwọn wá titi nwọn fi de Apii Foroni, ati Arojẹ mẹta, lati pade wa: nigbati Paulu si ri wọn, o dupẹ lọwọ Ọlọrun, o mu ọkàn le.
16. Nigbati awa si de Romu, balogun ọrún fi awọn ondè le olori ẹṣọ́ lọwọ: ṣugbọn nwọn jẹ ki Paulu ki o mã dagbe fun ara rẹ̀ pẹlu ọmọ-ogun ti ṣọ́ ọ.
17. O si ṣe, lẹhin ijọ mẹta, Paulu pè awọn olori Ju jọ: nigbati nwọn si pejọ, o wi fun wọn pe, Ará, biotiṣe pe emi kò ṣe ohun kan lòdi si awọn enia, tabi si iṣe awọn baba wa, sibẹ nwọn fi mi le awọn ara Romu lọwọ li ondè lati Jerusalemu wá.
18. Nigbati nwọn si wádi ọ̀ran mi, nwọn fẹ jọwọ mi lọwọ lọ, nitoriti kò si ọ̀ran ikú lara mi.
19. Ṣugbọn nigbati awọn Ju sọ̀rọ lòdi si i, eyi sún mi lati fi ọ̀ran mi lọ Kesari; kì iṣe pe mo ni nkan lati fi orilẹ-ède mi sùn si.
20. Njẹ nitori ọ̀ran yi ni mo ṣe ranṣẹ pè nyin, lati ri nyin, ati lati ba nyin sọ̀rọ: nitoripe nitori ireti Israeli li a ṣe fi ẹ̀wọn yi dè mi.