O si ṣe, lẹhin ijọ mẹta, Paulu pè awọn olori Ju jọ: nigbati nwọn si pejọ, o wi fun wọn pe, Ará, biotiṣe pe emi kò ṣe ohun kan lòdi si awọn enia, tabi si iṣe awọn baba wa, sibẹ nwọn fi mi le awọn ara Romu lọwọ li ondè lati Jerusalemu wá.