7. Àwọn aṣọ́de rí mibí wọ́n ti ń rìn káàkiri ìlú;wọ́n lù mí, wọ́n ṣe mí léṣe,wọ́n sì gba ìborùn mi.
8. Mo rọ̀ yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,bí ẹ bá rí olùfẹ́ mi,ẹ bá mi sọ fún un pé:Àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.
9. Kí ni olùfẹ́ tìrẹ fi dára ju ti àwọn yòókù lọ?Ìwọ arẹwà jùlọ láàrin àwọn obinrin?Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju ti àwọn yòókù lọ?Tí o fi ń kìlọ̀ fún wa bẹ́ẹ̀?
10. Olùfẹ́ mi lẹ́wà pupọ, ó sì pupa,ó yàtọ̀ láàrin ẹgbaarun (10,000) ọkunrin.
11. Orí rẹ̀ dàbí ojúlówó wúrà,irun rẹ̀ lọ́, ó ṣẹ́ léra wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ó dúdú bíi kóró iṣin.
12. Ojú rẹ̀ dàbí àwọn àdàbà etí odò,tí a fi wàrà wẹ̀, tí wọ́n tò sí bèbè odò.
13. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ dàbí ebè òdòdó olóòórùn dídùn,tí ń tú òórùn dídùn jáde.Ètè rẹ̀ dàbí òdòdó lílì,tí òróró òjíá ń kán níbẹ̀.
14. Ọwọ́ rẹ̀ dàbí ọ̀pá wúrà,tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí lára.Ara rẹ̀ dàbí eyín erin tí ń dántí a fi òkúta safire bò.
15. Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí òpó alabasitatí a gbé ka orí ìtẹ́lẹ̀ wúrà.Ìrísí rẹ̀ dàbí òkè Lẹbanoni, ó rí gbọ̀ngbọ̀nràn bí igi Kedari.