9. O ti kó sí mi lẹ́mìí, arabinrin mi, iyawo mi,ẹ̀ẹ̀kan náà tí o ti ṣíjú wò mí,pẹlu nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó wà lọ́rùn rẹ,ni o ti kó sí mi lórí.
10. Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó! Arabinrin mi, iyawo mi,ìfẹ́ rẹ dùn ju waini lọ.Òróró ìkunra rẹ dára ju turari-kí-turari lọ.
11. Oyin ní ń kán ní ètè rẹ, iyawo mi,wàrà ati oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ,òórùn dídùn aṣọ rẹ dàbí òórùn Lẹbanoni.
12. Arabinrin mi dàbí ọgbà tí a ti ti ìlẹ̀kùn rẹ̀.Ọgbà tí a tì ni iyawo mi;àní orísun omi tí a tì ni ọ́.
13. Àwọn ohun ọ̀gbìn inú rẹ tí ń sọ dàbí ọgbà pomegiranate,tí ó kún fún èso tí ó dára jùlọ,àwọn bíi igi hena ati nadi;
14. igi nadi ati Safironi, Kalamusi ati Sinamoni,pẹlu oríṣìíríṣìí igi turari,igi òjíá, ati ti aloe,ati àwọn ojúlówó turari tí òórùn wọn dára jùlọ.
15. Ọgbà tí ó ní orísun omi ni ọ́,kànga omi tútù,àní, odò tí ń ṣàn, láti òkè Lẹbanoni.