7. Mo kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,ní orúkọ egbin, ati ti àgbọ̀nrín pé,ẹ kò gbọdọ̀ jí ìfẹ́ títí yóo fi wù ú láti jí.
8. Mo gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi, wò ó! Ó ń bọ̀,ó ń fò lórí àwọn òkè ńlá,ó sì ń bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké.
9. Olólùfẹ́ mi dàbí egbin,tabi ọ̀dọ́ akọ àgbọ̀nrín.Wò ó! Ó dúró lẹ́yìn ògiri ilé wa,ó ń yọjú lójú fèrèsé,ó ń yọjú níbi fèrèsé kékeré tí ó wà lókè.
10. Olùfẹ́ mi bá mi sọ̀rọ̀, ó wí fún mi pé,“Dìde, olùfẹ́ mi, arẹwà mi,jẹ́ kí á máa lọ.”
11. Àkókò òtútù ti lọ,òjò sì ti dáwọ́ dúró.
12. Àwọn òdòdó ti hù jáde,àkókò orin kíkọ ti tó,a sì ti ń gbọ́ ohùn àwọn àdàbà ní ilẹ̀ wa.
13. Àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń so èso,àjàrà tí ń tanná,ìtànná wọn sì ń tú òórùn dídùn jáde.Dìde, olùfẹ́ mi, arẹwà mi,jẹ́ kí á máa lọ.
14. Àdàbà mi, tí ó wà ninu pàlàpálá òkúta,ní ibi kọ́lọ́fín òkúta,jẹ́ kí n rójú rẹ, kí n gbọ́ ohùn rẹ,nítorí ohùn rẹ dùn, ojú rẹ sì dára.
15. Mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ wọ̀n-ọn-nì,àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèké tí wọn ń ba ọgbà àjàrà jẹ́,nítorí ọgbà àjàrà wa tí ń tanná.
16. Olùfẹ́ mi ni ó ni mí, èmi ni mo sì ni olùfẹ́ mi,ó ń da àwọn ẹran rẹ̀, wọn ń jẹko láàrin òdòdó lílì.
17. Tún pada wá! Olùfẹ́ mi,títí ilẹ̀ yóo fi mọ́,tí òjìji kò ní sí mọ́.Pada wá bí egbin ati akọ àgbọ̀nrín,lórí àwọn òkè págunpàgun.