Orin Dafidi 89:6-22 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Nítorí ta ni a lè fi wé ọ ní ọ̀run, OLUWA?Ta ni ó dàbí OLUWA láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run?

7. Ọlọrun, ìwọ ni a bẹ̀rù ninu ìgbìmọ̀ àwọn eniyan mímọ́,o tóbi, o sì lẹ́rù ju gbogbo àwọn tí ó yí ọ ká lọ?

8. OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, ta ló lágbára bíi rẹ?OLUWA, òtítọ́ rẹ yí ọ ká.

9. Ò ń jọba lórí òkun tí ń ru;nígbà tí ìgbì rẹ̀ bá ru sókè, ìwọ ni ò ń mú kí ó rọlẹ̀.

10. Ìwọ ni o wó Rahabu mọ́lẹ̀ bí òkú ẹran;o fi ọwọ́ agbára rẹ fọ́n àwọn ọ̀tá rẹ ká.

11. Tìrẹ ni ọ̀run, tìrẹ sì ni ayé pẹlu;ìwọ ni o tẹ ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ dó.

12. Ìwọ ni o dá àríwá ati gúsù,òkè Tabori ati òkè Herimoni ń fi ayọ̀yin orúkọ rẹ.

13. Alágbára ni ọ́;agbára ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;o gbé ọwọ́ agbára rẹ sókè.

14. Òdodo ati ẹ̀tọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ;ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ ń lọ ṣiwaju rẹ.

15. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó mọ ìhó ayọ̀ nnì,àwọn tí ń rìn ninu ìmọ́lẹ̀ ojurere rẹ, OLUWA,

16. àwọn tí ń yọ̀ nítorí orúkọ rẹ tọ̀sán-tòru,tí sì ń gbé òdodo rẹ lárugẹ.

17. Nítorí ìwọ ni ògo ati agbára wọn;nípa ojurere rẹ sì ni a ti ní ìṣẹ́gun.

18. Dájúdájú, OLUWA, tìrẹ ni ààbò wa;ìwọ, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ọba wa.

19. Ní ìgbàanì, o sọ ninu ìran fún olùfọkànsìn rẹ pé,“Mo ti fi adé dé alágbára kan lórí,mo ti gbé ẹnìkan ga tí a yàn láàrin àwọn eniyan.

20. Mo ti rí Dafidi, iranṣẹ mi;mo ti fi òróró mímọ́ mi yàn án;

21. kí ọwọ́ agbára mi lè máa gbé e ró títí lae,kí ọwọ́ mi sì máa fún un ní okun.

22. Ọ̀tá kan kò ní lè borí rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan burúkú kò ní tẹ orí rẹ̀ ba.

Orin Dafidi 89