6. O ti fi mí sinu isà òkú tí ó jìn pupọ,ninu òkùnkùn, àní ninu ọ̀gbun.
7. Ọwọ́ ibinu rẹ wúwo lára mi,ìgbì ìrúnú rẹ sì bò mí mọ́lẹ̀.
8. O ti mú kí àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi fi mí sílẹ̀;mo sì ti di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn:mo wà ninu àhámọ́, n kò sì lè jáde;
9. ojú mi ti di bàìbàì nítorí ìbànújẹ́.Lojoojumọ ni mò ń ké pè ọ́, OLUWA;tí mò ń tẹ́wọ́ adura sí ọ.
10. Ṣé òkú ni o óo ṣe iṣẹ́ ìyanu hàn?Ṣé àwọn òkú lè dìde kí wọ́n máa yìn ọ́?
11. Ṣé a lè sọ̀rọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ninu ibojì?Àbí ẹnìkan lè sọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ ninu ìparun?
12. Ṣé a lè rí iṣẹ́ ìyanu rẹ ninu òkùnkùn ikú?Àbí ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ wà ní ilẹ̀ àwọn tí a ti gbàgbé?
13. Ṣugbọn OLUWA, èmi ń ké pè ọ́;ní òwúrọ̀ n óo gbadura sí ọ.
14. OLUWA, kí ló dé tí o fi ta mí nù?Kí ló dé tí o fi ojú pamọ́ fún mi?
15. Láti ìgbà èwe mi ni a tí ń jẹ mí níyà,tí mo sì fẹ́rẹ̀ kú,mo ti rí ìjẹníyà rẹ tí ó bani lẹ́rù;agara sì ti dá mi.
16. Ìrúnú rẹ bò mí mọ́lẹ̀;ẹ̀rù rẹ sì bà mí dójú ikú.
17. Wọ́n yí mi ká tọ̀sán-tòru bí ìṣàn omi ńlá;wọ́n ká mi mọ́ patapata.