1. Ọlọrun, kí ló dé tí o fi ta wá nù títí ayé?Kí ló dé tí inú rẹ fi ń ru sí àwa aguntan pápá rẹ?
2. Ranti ìjọ eniyan rẹ tí o ti rà ní ìgbà àtijọ́,àwọn ẹ̀yà tí o rà pada láti fi ṣe ogún tìrẹ;ranti òkè Sioni níbi tí o ti ń gbé rí.
3. Rìn káàkiri kí o wo bí gbogbo ilẹ̀ ti di ahoro,wo bí ọ̀tá ti ba gbogbo nǹkan jẹ́ ninu ibi mímọ́ rẹ.
4. Àwọn ọ̀tá rẹ bú ramúramù ninu ilé ìsìn rẹ;wọ́n ta àsíá wọn gẹ́gẹ́ bí àmì ìṣẹ́gun.
5. Wọ́n dàbí ẹni tí ó gbé àáké sókè,tí ó fi gé igi ìṣẹ́pẹ́.
6. Gbogbo pákó tí a fi dárà sí ara ògirini wọ́n fi àáké ati òòlù fọ́.
7. Wọ́n jó ibi mímọ́ rẹ kanlẹ̀;wọ́n sì ba ilé tí a ti ń pe orúkọ rẹ jẹ́.
8. Wọ́n pinnu lọ́kàn wọn pé, “A óo bá wọn kanlẹ̀ patapata.”Wọ́n dáná sun gbogbo ilé ìsìn Ọlọrun tí ó wà ní ilẹ̀ náà.
9. A kò rí àsíá wa mọ́,kò sí wolii mọ́;kò sì sí ẹnìkan ninu wa tí ó mọ bí ìṣòro wa yóo ti pẹ́ tó.
10. Yóo ti pẹ́ tó, Ọlọrun, tí ọ̀tá yóo máa fi ọ́ ṣẹ̀fẹ̀?Ṣé títí ayé ni ọ̀tá yóo máa gan orúkọ rẹ ni?
11. Kí ló dé tí o ò ṣe nǹkankan?Kí ló dé tí o káwọ́ gbera?
12. Ọlọrun, ìwọ ṣá ni ọba wa láti ìbẹ̀rẹ̀ wá;ìwọ ni o máa ń gbà wá là láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè.