1. OLUWA, ìwọ ni mo sá di,má jẹ́ kí ojú tì mí lae;gbà mí, nítorí olóòótọ́ ni ọ́.
2. Dẹ etí sí mi, yára gbà mí.Jẹ́ àpáta ààbò fún mi;àní ilé ààbò tó lágbára láti gbà mí là.
3. Ìwọ ni àpáta ati ilé ààbò mi;nítorí orúkọ rẹ, máa tọ́ mi kí o sì máa fọ̀nà hàn mí.
4. Yọ mí kúrò ninu àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ dè mí,nítorí ìwọ ni ẹni ìsádi mi.
5. Ìwọ ni mo fi ẹ̀mí mi lé lọ́wọ́,o ti rà mí pada, OLUWA, Ọlọrun, olóòótọ́.
6. Mo kórìíra àwọn tí ń bọ oriṣa lásánlàsàn,ṣugbọn OLUWA ni èmi gbẹ́kẹ̀lé.
7. N óo máa yọ̀, inú mi óo sì máa dùn,nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;nítorí pé o ti rí ìpọ́njú mi,o sì mọ ìṣòro mi.
8. O ò fi mí lé ọ̀tá lọ́wọ́,o sì ti fi ẹsẹ̀ mi lé ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.
9. Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí pé mo wà ninu ìṣòro.Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì;àárẹ̀ sì mú ọkàn ati ara mi.
10. Nítorí pé ìbànújẹ́ ni mo fi ń lo ayé mi;ìmí ẹ̀dùn ni mo sì fi ń lo ọdún kan dé ekeji.Ìpọ́njú ti gba agbára mi;gbogbo egungun mi sì ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ.
11. Ẹni ẹ̀gàn ni mí láàrin gbogbo àwọn ọ̀tá mi,àwòsọkún ni mí fún àwọn aládùúgbò.Mo di àkòtagìrì fún àwọn ojúlùmọ̀ mi,àwọn tí ó rí mi lóde sì ń sá fún mi.
12. Mo di ẹni ìgbàgbé bí ẹni tí ó ti kú;mo dàbí àkúfọ́ ìkòkò.