Orin Dafidi 16:5-7 BIBELI MIMỌ (BM)

5. OLUWA, ìwọ ni ìpín mi, ìwọ ni mo yàn;ìwọ ni ò ń jẹ́ kí ọ̀ràn mi fìdí múlẹ̀.

6. Ìpín tí ó bọ́ sí mi lọ́wọ́ dára pupọ;ogún rere ni ogún ti mo jẹ.

7. Èmi óo máa yin OLUWA, ẹni tí ó ń fún mi ní òye;ọkàn mi ó sì máa tọ́ mi sọ́nà ní òròòru.

Orin Dafidi 16