10. Ìwọ ni o mú kí àwọn orísun máa tú omi jáde ní àfonífojì;omi wọn sì ń ṣàn láàrin àwọn òkè.
11. Ninu omi wọn ni gbogbo ẹranko tí ń mu,ibẹ̀ sì ni àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń rẹ òùngbẹ.
12. Lẹ́bàá orísun wọnyini àwọn ẹyẹ ń gbé,wọ́n sì ń kọrin lórí igi.
13. Láti ibùgbé rẹ lókè ni o tí ń bomi rin àwọn òkè ńlá.Ilẹ̀ sì mu àmutẹ́rùn nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
14. Ó ń mú kí koríko dàgbà fún àwọn ẹran láti jẹ,ati ohun ọ̀gbìn fún ìlò eniyan,kí ó lè máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀;
15. ati ọtí waini tí ń mú inú eniyan dùn,ati epo tí ń mú ojú eniyan dán,ati oúnjẹ tí ń fún ara lókun.
16. Àwọn igi OLUWA ń mu omi ní àmutẹ́rùn,àní àwọn igi kedari Lẹbanoni tí ó gbìn.
17. Lórí wọn ni àwọn ẹyẹ ń tẹ́ ìtẹ́wọn sí,àkọ̀ sì ń kọ́ ilé rẹ̀ sórí igi firi.
18. Òkè gíga ni ilé ewúrẹ́ igbó,abẹ́ àpáta sì ni ibùgbé ehoro.
19. O dá òṣùpá láti máa sàmì àkókò,oòrùn sì mọ àkókò wíwọ̀ rẹ̀.
20. O mú kí òkùnkùn ṣú, alẹ́ sì lẹ́,gbogbo ẹranko ìgbẹ́ sìń jẹ kiri.
21. Àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun ń bú fún ìjẹ,wọ́n ń wo ojú Ọlọrun fún oúnjẹ.
22. Nígbà tí oòrùn bá là, wọn á wọ́ lọ;wọn á lọ dùbúlẹ̀ sinu ihò wọn.
23. Ọmọ eniyan á sì jáde lọ síbi iṣẹ́ rẹ̀,á lọ síbi làálàá rẹ̀ títí di àṣáálẹ́.
24. OLUWA, ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ!Ọgbọ́n ni o fi dá gbogbo wọn.Ayé kún fún àwọn ẹ̀dá rẹ.
25. Ẹ wo òkun bí ó ti tóbi tí ó sì fẹ̀,ó kún fún ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dá,nǹkan abẹ̀mí kéékèèké ati ńláńlá.
26. Ibẹ̀ ni ọkọ̀ ojú omi ń gbà lọ,ati Lefiatani tí o dá láti máa ṣeré ninu òkun.
27. Ojú rẹ ni gbogbo wọn ń wò,fún ìpèsè oúnjẹ ní àkókò.