6. Ó mú Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ jáde, ó fi omi wẹ̀ wọ́n.
7. Ó gbé ẹ̀wù náà wọ Aaroni, ó sì dì í ní àmùrè rẹ̀, ó gbé aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ wọ̀ ọ́ ati efodu rẹ̀, ó sì fi ọ̀já efodu tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà dáradára sí lára dì í lámùrè.
8. Ó mú ìgbàyà, ó so ó mọ́ ọn láyà, ó sì fi Urimu ati Tumimu sí ara ìgbàyà náà.
9. Ó fi fìlà dé e lórí, ó fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà, adé mímọ́ tíí ṣe àmì ìyàsímímọ́, sí iwájú fìlà náà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún Mose.
10. Mose gbé òróró ìyàsímímọ́, ó ta á sí gbogbo ara Àgọ́ náà ati ohun gbogbo tí ó wà ninu rẹ̀, ó sì yà wọ́n sí mímọ́.
11. Ó mú lára òróró náà ó wọ́n ọn sí ara pẹpẹ nígbà meje, ó ta á sórí pẹpẹ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò tí wọ́n wà níbẹ̀, ati agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀; ó fi yà wọ́n sí mímọ́.
12. Ó ta díẹ̀ ninu òróró náà sí Aaroni lórí láti yà á sí mímọ́.
13. Mose kó àwọn ọmọ Aaroni, ó wọ̀ wọ́n lẹ́wù, ó sì dì wọ́n ní àmùrè, ó dé wọn ní fìlà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.
14. Lẹ́yìn náà, ó mú mààlúù ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ jáde, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin gbé ọwọ́ lé e lórí.
15. Mose pa mààlúù náà, ó gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ó ti ìka bọ̀ ọ́, ó sì fi sí ara àwọn ìwo pẹpẹ yípo, ó fi yà wọ́n sí mímọ́. Ó da ẹ̀jẹ̀ yòókù sídìí pẹpẹ fún ètùtù, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe yà wọ́n sí mímọ́.
16. Lẹ́yìn náà, ó mú gbogbo ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú mààlúù náà, ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀, ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tó wà lára wọn, ó sun wọ́n lórí pẹpẹ.
17. Ṣugbọn ó dáná sun ara ẹran akọ mààlúù náà, ati awọ rẹ̀, ati ìgbẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn ibùdó náà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.